KidsOut World Stories

Ijapa Ati Awon Omo Orukan Meta Abimbola Alao    
Previous page
Next page

Ijapa Ati Awon Omo Orukan Meta

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

Ijapa Ati Awon Omo Orukan Meta

Orúkọ mi ni Abimbọ́lá Àlàó

 

 

 

 

 

 

Ni igba laelae, awon omo orukan meta kan wa ti oruko won nje Otarun, Akope, ati Awekun. Awon omo yi pinnu lati bere ise owo, won si tọ Ijapa lọ; nitori lati igbati awon obi won ti fi aye sile Ijapa ni o ma a ntoju won ti o si ma a ngba won ni iyanju leekokan.

Awon meteeta f’ori le ile Ijapa. Nigbati won de’be, won ki ii oun na si ki won daadaa. O fun won ni obi, gbogbo won si joko ni abe igi niwaju ile re.

Otarun ni o koko soro. O ni, ‘Emi ati awon aburo mi fe nilati dupe lowo re gidigidi, Ijapa, fun akitiyan re lori wa latigba ti awon obi wa ti fi aye sile. Ohun ti a muwa sodo re loni ni wipe awa fe ki o gba wa niyanju nipa oro ise. A fe lati lọ kọ ise.

Ijapa mi kanle, o woke o wole. O ni e seun, mo dupe lowo yin wipe, e ò f’oju di agba. Inu mi si dun lopolopo pe ẹ nfe lati ko ise. Emi yo si gba yin niyanju wipe ki e wa bami da owo po, ki e wa ba mi sise.

Awon omokunrin meta yi woju ara won. Akope dahun pe, ‘iyen ni wipe onisowo ni iwo Ijapa, awa ko mo.

Ijapa rerin o ni, ‘Onisowo ni mi. Sugbon ise opolo ni òwò temi ki i se ise agbara. E ko se akiyesi pe nkò ni oko, nkò si ni abà; emi kii si ra oja, nki i si ita. N ko si se ise ijoba, beeni n o loga. Sugbon, mo nje, mo n mu laise alaini ohunkohun.

Awon omo iya yi tun wo ara won tiyanutiyanu, won si tun wo Ijapa tifuratifura. Ijapa dahun o ni, ‘Kilode ti e fi nwo mi bi enipe mo gbe ida soke lati fi be yin lori? Se e ro pe alonilowogba nimi ni? Emi kii ise janduku o. O kan je pe ohunkohun ti mo ba fe, n o ri gba.

Awon omokunrin yi ko mo ohun ti won o fi fesi. Lehin iseju die, Otarun dide o ni, ‘awa yio lo ro oro ti o fi lọ wa wo, awa yio si fesi bo ba d’ola’.
Ni ojo keji, Otarun nikan lo lo si ile Ijapa, o s iwi fun pe, ‘Emi ati aburo mi ti ro oro ti iwo fi lo wa, a si dupe lowo re fun imoran na. Sugbon a ko le e ba o sise, nitoripe olotito eniyan ni awa, a si nfe lati fi owo wa sise ni asekara. Inu bi Ijapa, oju re si pon, o ni, ‘Alaimoore ni eyin omode wonyi. Se ohun ti ẹ ó fi soore latigba ti awon obi yin ti kuro laye niyen?’

Otarun dahun o wipe, ‘Beeni’. Ijapa si wi fun wipe, Bi o ba wa ri be o, emi Ijapa ti di ota yin, emi o si fi oju yin ri eemo.

Lehin ọ̀sẹ̀ die, awon omokunrin na bere si ko ise owo, won si sise karakara. Won se ise won laseyori; laipe Otarun bere si sise ode, o si se olokiki ninu ise re. Akope bere si ise emu dida; beeni Awe’kun sise apeja ti o si lokiki laarin ilu, nitori eja re a ma tobi.

Ni ojo kan, Ijapa lo si aafin oba lati so fun oba wipe awon omokunrin yi fe da ilu ru. Eyi ya oba lenu, o si ni ki Ijapa se alaye oro. Ijapa dahun wipe awon omokunrin na nparo kaakiri wipe awon le se ohun abami ti eda kan ko le e se ri. Won ni awon le ta ofa ti yio kan ofurufu. Okan ni oun le e gun igi ope laini igbà. Eyi ti o ti e yàmi lenu julo, oun ni eleyi abigbehin, o ni oun le e we okun ja laarin iseju kan. Ha! Kabiyesi, ohun ti o nbamileru nipe, awon ilu ti o yi wa ka, ti won ba gbo oro ti awon omokunrin yi nso nipa pe awon le e se ise abami yi, ilu wa yio di ilu awon oniro eleyi si lee mu abuku wa fun wa, Kabiyesi. Ni Ijapa ba pari oro re. Inu bi oba, o si ranse pe awon omo meta wonyi. Nigbati won de aafin, o pase fun won pe lehin ojo meje, Otarun gbodo mu ofa wa lati ta, ki ofa na kan ofurufu. Akope gbodo gun igi laisi igbà. à Awekun yio si we okun ja laarin iseju kan. Ha! Awon omokunrin yi be oba, won ni awon ko mo idi oro ti oba fi lo awon yi, awon ò si mo idi ti oba fi nbinu si awon. Oba dahun pe a ti fi tó oun leti wipe awon omokunrin yi nfon-nu pe awon le e se ohun abami. Oun si fe ki won se gbogbo nnkan ti won nfon-nu pe awon le se. Lehin eyi, oba pase fun awon dongari re pe ki won maa sọ́ awon omo iya meteeta na, won ko si gbodo jeki won kuro laarin ilu.

Inu awon omokunrin meteeta na baje gbaa; won mo pe Ijapa ni o wa nidi oro yi, sugbon won o mo ohun ti won le e se. Oba tile ti pase f’awon dongari re pe won gbodo ma a sọ́ won, won ò si gbodo kuro laarin ilu. Pelu ironu ati iteriba ni awon meteeta fi kuro ni aafin lojo na.

Ni owuro kutukutu ojo kan, awon omokunrin yi taji loju orun; orin eye abami kan lo ji won.  Won sure dide, won si ferese ile won lati wo eye yi. Eye na le gongo sori igi ti o wa leba ile won, o si nkorin pe:

Omode meta nsere
Ere o o o o ere ayo

Omode meta nsere
Ere o o o o ere ayo

Okan l’oun o ta’run
Ere o o o o ere ayo

Okan l’oun o g’agbon
Ere o o o o ere ayo

Okan l’oun o we’kun
Ere o o o o ere ayo

Ota’run, Og’agbon, Owe’kun
Ere o o o o ere ayo

Ota’run, Og’agbon, Owe’kun
Ere o o o o ere ayo

Ota’run, Og’agbon, Owe’kun
Ere o o o o ere ayo

Nigbati eye yi pari orin re, o fò lọ, sugbon awon omokunrin yi dake jẹ̃ lojukanna nibiti won wa; won si duro si i.

Otarun taju kan, o si ri ọfà ati ọrun kan legbe ibiti eye na ti fò kuro; legbe ibe, o ri igbà, ati oja iluwe kan lojukanna nibiti eye na ti fo kuro. Awon omokunrin yi sare lo sibe, onikaluku mu ohun ti o jo mo ise re, won si wole lo.

Laipe, won lo si aafin lati lo ri oba; oba si pase fun won pe, ni okookan ki won bere si se ohun ti fon-nu lati se. Ó koju si Otarun o wipe, ‘Iwo ta ofa, ki o si kan ofurufu. Ni kia mosa, Otarun mu orun ati ofa re, ọrun ti eye yi ti fi sile, o je orun abami, ko si enikeni to le e ri, yato si awon omo iya meta yi. Otarun mu ofa re ati orun na, o ta ofa, laipe ofa yi fo lo o si kan oju-orun. Gbogbo awon eeyan to wa nibe bere si patewo, ti won si nkorin ti won si nlulu ti won si njo, won wipe a o ri ru eleyi ri.

Lehinna, oba koju si Akope, o ni ‘O ya o, Akope. O ni lati gun ope laisi igba’ Akope mu igba ti o ti muwa latile, eleyi ti eye abami na ti fi sile fun won. O mu igba na, o si bere si gun igi ope; o nsare gun, o ngun tagbaratagbara. Laipe, laijina o gun ope jari laisi igba. Gbogbo awon eniyan tun bere si kigbe, won npatewo.

Oba ti bere si dake sii, ara re si bere si bale. O ru loju, ‘bawo ni awon omo yi se le se awon ohun abami yi?’ Sugbon laipe, laijina o koju si Awe’kun o ni, O ya o, mu wa lo si eti omi, o ni lati we okun ja.

Laarin iseju kan, Awe’kun saaju, gbogbo ilu si tẹle. O mu oja abami ti eye na ti fi sile, eleyi to se pe oun ati awon egbon re nikan ni o le e ri, ti ko si enikeni ti o tun le e ri. O mu sapa. Nigbati won de ibi eti omi, o kán lu omi, o si bere si luwe. O luwe lo soke sodo, laarin iseju kan, o ti luwe tan. Gbogbo ilu npariwo, won nho yee, won nse ha! Won ni a ko ri iru eleyi ri o. Ẹnu ya gbogbo won, bawo lo se se e?

Bi eleyi ti nsele, Ijapa ro pe ko si enikeni ti o ri oun. O si yọ́ kọ́rọ́, o fe ma a salo. Sugbon okan ninu awon dongari oba kii mole, o gbe, o ni, ‘Nibo niwo ro pe iwo nlo? Iwo eranko buburu yi. Wa nibi!’ O gbe si ejika re, gbogbo ilu si kori si aafin oba. Awon okunrin adugbo, won gbe awon omokunrin yi si ejika, won nkorin, won nlulu, won nho yeee, ilu gbogbo ilu ndun lopolopo fun ohun nlanla ti awon omo wonyi se.

Nigbati won de aafin, oba so funwon wipe, oun fe be won pe ki won má binu esun ti oun fi kan won. Oba koju si Ijapa o ni, ‘Ijapa, eranko buburu ni o; ewon ti o fe ki awon omokunrin yi lo, iwo ni yio lo si ewon na. Ó wa koju si awon omokunrin na o ni, ‘Mo fe ki eyin meteeta ki e di oloye ni aafin mi’. Gbogbo ilu ho yeee! Won nkorin, awon onilu si nlu ilu, won nyo; won si nba awon omokunrin yi yo fun ohun nlanla ti won se.

Enjoyed this story?
Find out more here