KidsOut World Stories

BI Ikarawun Ijapa Se Ri Wọ́ngan-wọ̀ngan    
Previous page
Next page

BI Ikarawun Ijapa Se Ri Wọ́ngan-wọ̀ngan

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

BI Ikarawun Ijapa Se Ri Wọ́ngan-wọ̀ngan 

Orúkọ mi ni Abimbọ́lá Àlàó.

 

 

 

 

  

  

*

Itan yi da lori idi ti ikarawun ijapa fi ri wọ́ngan-wọ̀ngan.

Ni igba laelae iyan buburu kan mu ni ilu awon eranko, ko si si ounje rara. Nitori idi eyi Ijapa ko ri ounje fun awon ẹbi rẹ, ebi si npa won gidigidi. Ni ojọ́ kan Ijapa pinnu lati wa ounje lo si aarin oja, sugbon nigba to de bẹ, ko ri ohunkohun. Bi Ijapa se fe yipada lati pada si ile re ni o se akiyesi Ehoro, ti o nyan kandukandu kaakiri oja. Oju Ehoro ndan bi eniti iyan ko ja. Awo re si tutu minijojo. Ijapa pinnu lati se iwadi ibiti Ehoro ti nri ounje je ti okan re fi bale tobayi. Nitorina o teriba o si bere si sun ekun eke. Nigbati Ehoro fere de odo re o gbohun soke, o nko họ́-ù-họ́-ù.

Ehoro gbo iro ekun ijapa o si sure lo sodo re. o ni ‘Kilo de, ore mi?’

Ijapa dahun pe, ‘Baba mi wa ni ile iwosan. Iyawo mi loyun omo keta, sugbon ebi npaa lọ́pọ́polopo. Ni ale ana ni a gbọ́ pe iya iyawo mi nku lo nitori iyan yi. Mi o mọ’hun ti mo le se o.’

‘Hun-un’ Ehoro mi kanle o ni, ‘Ijapa, gbogbo eranko lo mo o si olọ́gbọ́n ewe. Emi o mo bi n o le ran o lọ́wọ́ o.’

Sugbon Ijapa olọ́gbọ́n ewe wa ona lati tan Ehoro ki o le ran oun lọ́wọ́.

Ehoro si gba. Ehoro ni o daa, emi o ran o lowo, pade mi ni eti odo Ọ̀rẹ̀ ni ale yi. Mo lero pe n o ni kabamo oore ti mo fẹ se fun o.

Ni ale ojọ́ na, Ijapa mu irin ajo pon lo si eti odo Ọ̀rẹ̀ nibiti Ehoro ti nduro dee. Awon mejeji si mura, won mori le igbo. Laipe lo titi, won de ibikan ti o teju perese, nibiti ko si igi igbo pupo.

Ehoro koju si Ijapa o wipe, ‘o nilati se ileri fun mi pe o ò ni tú asiri ohun ti mo fe fi han ọ yi fun enikeni.’ Ijapa se ileri fun. Ehoro wa koju si oke orun o bere si korin pe:

“Iya, iya taakun wa lẹ o
A lu janjan ki jan
Iya, iya taakun wa lẹ o
A lu janjan ki jan.”

Lesekese, okun funfun kan bere si sokale lati oju ofurufu.

Ehoro gba okun mu o si bere si pon lo soke.

Ijapa na si se bẹẹ gẹgẹ.

Nigbati won de oke sanmo, won ri ilekun kan ti a fi ikuuku se.

Ilekun yi, o lewa lopolopo. Ehoro agbalagba kan si wa lati pade won.

Ehoro ki iya re, o ni, ‘Iya mi, mo mu ore mi wa, Ijapa loruko re. O fe lati wa bawa jeun ale ni.’

Iya Ehoro ki Ijapa kaabo. O si mu won wole. Iya Ehoro tip ese orisirisi ounje sile fun won. Eso orisirisi, eja, aladun, iresi, iyan, obe aladidun, orisirisi ohun mimu. Ijapa ri ounje yi o si bere si jeun lesekese. O njeun bi wobia. Ehoro gba niyanju pe ki o mase je ounje ajeki, ki o ba le rin pada si ile re. Sugbon ijapa ko da lohun; o jeun titi ti iku re fi tobi rọ̀bọ̀tọ̀, ti ko si le mi kanle. Lehin eyi Ehoro wi fun Ijapa wipe asiko to lati ma a lo sile. Ijapa dide o si mu ori le enu ona. Iya Ehoro ke si wipe, ‘Iwo ko ni mu ounje die lo fun awon ebi re ni?’ sugbon Ijapa ko, o ni ounje ajeki ti oun je ko je ki oun le mu ounje kankan da ni.

Iya Ehoro na okun sile fun omo re ati Ijapa, won si pada sinu aginju. Awon mejeji si mori le ile won. Nigbati Ijapa olọ́gbọ́n ewe de ile, o rora bọ́ si ori ibusun re, o si sun lo fonfonfon fun wakati mejila. Nigbati o ji, ebi bere si paa, ebi na ko se e mu mora. Nitorina, o ro ninu ara re o ni, ‘Emi o pada lo si ile Ehoro. Ti mo ba de’be emi o mo ohun ti n o wi fun iya re.’ ijapa dide n’le, o morilegbo. Nigbati ijapa de inu igbo, o fi orin bo’nu, o bere si korin pe:

“Iya, iya taakun wa lẹ o
A lu janjan ki jan
Iya, iya taakun wa lẹ o
A lu janjan ki jan.”

Sugbon ohun ijapa se kọ̀-n-kọ̀, nitori eyi ko le korin na daadaa bi ti Ehoro.

Iya Ehoro gbo orin na, o si bere si fun ra, o ni, ‘Ohun eniti nkorin nisale yi ko jo ti omo mi, boya aare si n se e ni, tabi otutu nmu.’ Iya Ehoro ro ninu ara re. sugbon o pinnu lati ju okun sile. Inu Ijapa dun lopolopo nigbati o ri okun, o si yara bere si pon on. Sugbon bi o ti de idaji okun ni o gbo ohun enikan lehin re ti o nke tantan, ‘Nibo niwo Ijapa ro pe iwo nlo, iwo eranko buburu yi. Sokale kia!’ Ehoro kigbe pelu ibinu. O si kigbe pe, ‘Iya mi, Ijapa ti tan wa je o.’ Sugbon Ijapa ko duro, o bere si gun okun na tagbaratagbara bi o ti nronu ounje aladidun ti o wa loke. Ehoro bere si korin o ni:

“Iya, iya taakun wa lẹ o
A lu janjan ki jan
Iya, iya taakun wa lẹ o
A lu janjan ki jan an.”

Iya Ehoro gbo ohun omo re. ‘O ya a lenu, Họ́wù! Ohun omo mi leyi. Sugbon ta leni to korin lakọ́kọ́?’ Ni Kia, iya Ehoro yoju lati oke, o ri ijapa ti o npon okun tagbaratagbara, o sit un ri omo re to njuwo to si nso pe, ‘Iya mi, iya mi, Ijapa ti tan wa je o, f’obe sokun, f’obe sokun, f’obe re okun o.’

Iya Ehoro ko fi akoko sofo, o sare mu obe ogemorekeu kan to wa nitosi, o si bere si ge okun. Ni akoko, se lo dabi eni pe irin ni a fi se okun na, se lo le dan-in-dan-in. sugbon, se ni iya yi mura sise, o re o si fere re ja. Eru ba a pe bi Ijapa ba de oke o le se oun ni jamba ki o to bere si jeun. Bayi ni iya Ehoro se re okun na ti o si ja a si meji. Apa kan wa lowo ijapa bi o ti nsubu bo nile. Ategun gbe sihinsọ́hun titi o fi subulule ninu igbo; ikarawun ni Ijapa fi lule, ‘gbò’, eyi ni si fọ́. Ijapa daku lo rangbondon. Sugbọ́n lehin wakati die o taji, ara re si bale. O dide, o kori si ile re. lati ojọ́ na lo, ikarawun Ijapa ti o ti ndan minijojo teleri wa di afọ́ku, ko si pada si bi ti atijọ́ mọ́.

Enjoyed this story?
Find out more here