KidsOut World Stories

Kulumbu Yeye Abimbola Alao    
Previous page
Next page

Kulumbu Yeye

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

Kulumbu Yeye

 

 

Ni igba laelae, lehin-odi abule Jago, abo kiniun kan ati omo re wa ti oruko re nje Kako. Abo kiniun na feran omo re, ati pe lálaalẹ́ ko to sun, o maa korin, “Kulumbu Yeye” (Bouncy Baby).

Kulumbu yeye Oyeye kulumbu
Kulumbu yeye Oyeye kulumbu
A o fotun gbomo jo
Kulumbu yeye Oyeye kulumbu
A o fosi gbomo pon
Kulumbu yeye, oyeye kulumbu

Bi ọjọ́ ti nlo, Kako ati omo re feran ara won to je wipe won ko le e ya ara won, afi igba to di ojo kan.

Gegebi ise re, abo kiniun na mura lati sode ounje. Omo re fe te le o si wipe, “Iya, se ki nsode pelu re? o su mi lati ma a seregbe kaakiri ninu oorun.”

‘“Rara.” Abo kiniun tenumo “Bi o se mo, o nsoro sii lati ri ounje to dara nitosi ile. Loni mo fe se awari agbegbe tuntun maa si mu o lowo ti mo ba mọ̀ pe ko s’ewu.”

“O daa, Ma a duro de o nibiyi,” ni Kako wi pelu ibanuje bi o ti nwo iya re to npòóra sinu aginju. O duro de iya re ni gbogbo ojo na, okan re ko si bale nigbati o di ale ti iya re ko tii pada.

“Joo Olorun, pa iya mimo,” o gbadura, sugbon ki o to pari adura re, o gbọ iró nla bùùm!

Igbe na wo’nu eegun ehin lo. Bi ipatewo aara, o mi aginju na titi. Kako fo ninu eru.

“N ko fe ariwo bayen.” Iya re si wa nita ninu igbo. Oogun boo, o si bere si gbon lemolemo. “Kini ti ….kini ti …ti ariwo yen ba je iro ibon? Oh emi, kini ti iya ba ti …?” O duro o si gbetọmi. Ko le gba ero bee laye lokan re. Lairotele, o be sinu aginju.

Bo ti fe de’nu igbo, o ke pe iya re.

‘“Mama! Mama! Mama, nibo lo wa?”

Laipe o gburo ese lehin re o si yipo.

Arakunrin Kiniun re ni. “Ki lo nse nita nibiyi niwonikan, Kako? Awon igbo wonyi lewu fun omo kiniun bi ti e. ki i se papa isere niyi, se o mo.”

Kako gba ibawi, sugbon o nilati wa iya re. O wipe, “Mo nwa iya mi. O ti nsode latataaro, o si ti ma a ndari wa’le bi iru asiko bayi.

Kiniun wo pelu ironu. “O dami loju iya re yio wa lalaafia. Boya o sina ninu igbo. O mo bi ó ti kún si. Bayi sare pada lo sinu iho re bi mo ti nwa iya re lo.”

“Rara! Mo ntele o!”

Nkankan ninu ohun omo kiniun na jeki Kiniun mo wipe asan ni lati ma a ba jiyan. “Odaa, rii pe o duro timi pekipeki bi a ti nrin laarin aginju.”

Awon eranko mejeji na tesiwaju lati ma a wa abo kiniun na, laipe won ri apeere kan labe igi Iroko nla kan. Won sare siwaju, lati ri oku abo kiniun ninu ibu eje.

“Iya!” Bi Kako ti wo oku re, ko le panu de. O sunmo o si bere si faa soke.

“Iya, dide ko si jeka lo sile! Ile ti su! O ya! O ya!”

“Kako,’ ni Kiniun wi, ‘iya re ti ku. Nisisiyi jowo tele mi. Ma a seto lati gbe kuro nibiyi.”

“Rara! Ko seni to ma a yami kuro lodo re. O semi laanu, sugbon mi o ni kuro nibiyi.” Kato tenumo kiko jale re. O bere si korin kelekele.’ 

Aworan iku oro iya re wa lokan Kako’s. Gbogbo awon eranko lo nse daadaa si, won si ntoju re ti ko se alaini ohunkohun, sugbon ko si enito le ropo iya re owon. Ó sàárò re losan ati loru ati nigbati to si han si wipe oun ko ni rii mo, o bere si binu o si nkoro. Ó seleri pe lojo kan oun o gbesan lara omo eniyan to pa a. Ó pinnu lati gbesan nigbati oun ba di agbalagba kiniun.

‘Lehin opo odun Kako dagba o si di kiniun arewa, alagbara ati onigboya. Ni ale osupa ojo kan, o rá pálá jáde kuro ninu iho re o si lo si isẹti igbo. Ó mo pe ijade yi lewu. Olode le pa oun na; sibesibe o mo wipe ise ti oun fe se se pataki ju ààbò oun lo. O ti nduro de ojo ti oun o gbesan iku iya oun ati pe oun ko si ni yi okan pada lori eyi.

O gun ori oke giga kan o si koja awon odo meji ko to ri abule Lantoro. O gbooro ni jijina labe Okuta Olumo nla. Kako sare lo sibi ibudo na, sugbon bo ti sunmo tosi, ko sare mo. Dipo bee, o bere si yo kelekele ko ma ba a ji awon ara abule.

‘“Ma a fun ile kan tabi meji ni ibanuje iyanu,” o ro lokan, bayi o nse afihan awon eyin buburu ati eekanna to mu hanhan. “Ojo esan ti de fun awon ika eniyan to so mi di alainiya.”

O yara lo si apa ibiti awon ahere wa niwaju. O ri ina to njo baibai ninu okan lara awon ahere na. Ibiyi lo ti koko fe farahan gegebi alejo airotele.’

Kako rin sunmo ahere na. Laipariwo, o rin kaakiri ile na lo si ehinkule o si lugo sehin igi kan o ri ahere na bi oun ti nseto lati kolu won.

Lati oju ferese to wa legbe ile na o ri obirin kan to jade latinu okan lara awon yàrá na. O pon omo kekere sehin. Omo na fẹ́ẹ̀ to osu meji.

‘O rẹ iya kekere yi, ami pe o sàisùn ni gbogbo oru. ‘“Eyi ni anfaani mi,” Kako ro bee bi o ti ra pala jade nibiti o farapamo si lati fo mo lojiji iya ti ko nifura. O fi omo-ka’sẹ̀ rin si ilekun ehin o sigbe eekana osi soke lati fipá sii, sugbon nnkankan daduro. Orin kan ni!

‘Iya kekere na nkorin si omo re.

‘Kako di yin-yin. Ko tii gbo orin yen lati ale ojo ti won pa iya re. O ranti awon ojo ti o ko iru ohun orin na sii gegebi omo-owo. O nwo aworan iya re bo se ngbe ese ijo to npanilerin.

Lona ara, bi obirin na ti tesiwaju lati korin, ohun re bere si rẹ̀ silẹ̀, ti Kako si ngbo ohun iya re to ti ku; eyi si mu ko bẹ̀rẹ̀ si sokun. Lesekese, lo pinnu lati ma se tesiwaju pelu ipinnu re ti o si pinnu lati pada sinu igbo.

”N ko ro pe o f’ogbon yo lati so omo miran di alainiya nigbati mo mọ ipalara ti o rọ mọ idagbasoke mi,” ó rò bẹ́ ẹ̀. 

Opolopo odun lehin eyi, omode na dagba lati di odomokunri to lewa to si wulo lawujo. O feran awon eranko o si ja takuntakun fun idaabobo awon igbo ni agbegbe na. Ni ojo kan, awon ara ilu abule Lantoro pinnu pe won nfẹ ẹ gegebi oloye won, won si se ayeye nla lati bu ola fun olori won tuntun – oloye daadaa kan to sin awon eniyan re gidigidi ti ko si gbagbe awon ọrẹ rẹ, awon eranko igbo. O pase pe ko si enikeni to gbodo s’ọdẹ awon eranko to wa ninu ewu bii awon kiniun, àgùnfọn, ati awon erin; ati lati igbayen, awon eranko igbo ni idábòòbò ati alaafia.

 

 

 

mature lion painted

 

Enjoyed this story?
Find out more here