KidsOut World Stories

Ilu Ti Nkọrin Abimbọ́lá Àlàó    
Previous page
Next page

Ilu Ti Nkọrin

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

Ilu Ti Nkọrin

Orúkọ mi ni Abimbọ́lá Àlàó.

Itan yi da lori ilu ti nkorin.

 

 

 

 

 

 

 

 

Ni igba kan, omokunrin kan wa ti oruko re nje Atilola. Awon obi re feran re gidigidi nitoripe oun nikan ni won ni. Won kò si fi ohunkohun dùú; se ni won ma a nse ni ohun elege; won ki i fe ki enikeni ba a wi bi o tile huwa to buru. Nitori idi eyi Atilola ma a nse ise omo onibaje, ki i si gboran si enikeni lenu. Ni ojo kan ni igba akoro ojo, Atilola ni oun fe lo sere pelu awon ore oun ni ojule, iya re so wipe ko mase jinijini lo sibe. Sugbon gegebi ise re, Atilola kọ’ti ikun si amoran iya re o si wa awon ore re lo. Nigbati o de odo awon ore re, o sere lo si afonifoji lati lo wa oyin. Sugbon bi o se wo afonifoji ni won ripe ojo ti su ni oju orun, ààrá si bere si san, ‘paa’. Okan ninu awon ore Atilola daba wipe kawon pada lo sile ki ojo to bere si rọ. Awon eeyan ri i pe àbá yi dara, won si mura lati pada, sugbon Atilola so pe, ‘Emi o ni pada ntemi o, oyin ni mo wa debi emi ò si ni kuro nibi lai royin’.

‘Bawo la se fe ri oyin ninu ojo yi?’ Okan ninu awon ore re beere. B’emi o ba le ri oyin ninu omi, emi o duro t’ojo o fi da. Bi Atilola ti pari oro re ni ojo bere si fon. …won pada si abule won si fi òun nikan sile ko ma a wa oyin. Laipe, ojo bere si rọ, o si bere si di adagun omi kekere.

Atilola nfò sihin sohun bi alagemo, o njuwọ́ soke, sile o si nfowo gbe omi. Awon agbe to npada lo sile latinu oko so fun pe ki o kuro ninu ojo ki o ma a lo sinu abule. Sugbon nise ni omo alaigboran yi feju mo won, o nyo ahon siwon, o si nfiwon se yeye, o si njo ninu adagun omi bi ojo ti nro si.

Laipe àgbàrá ojo gba gbogbo afonifoji, Atilola ko si ri ibiti o le e sasi, o nfo kaakiri titi o fi ri igi odan kan ti o lọ si abe re. Sugbon bi ojo yi ti nposi, Atilola pinnu lati gun igi lo ki agbara ojo ma ba a gbe e lo. Ni kete ti o fe ma gun igi yi ni o kose ti o si subu sinu agbara ti omi si bere si gbee lo. Atilola fi igbe ta, sugbon ko si enito wa nitosi. Bi omi se ngbee lo, o ri awon igi weere ati igi titobi, o si nawo gan awon igi, sugbon nitori awon igi na lefo lori omi, ko wulo fun.

Atilola se akiyesi ile, o si kigbe ni ohun rara, ‘E gba mi ooo, E joo, e ran mi lowo,’ o nke si onile na ki o ran oun lowo; Ijapa ni o ngbe inu ile yi…

O si ferese re, o ri Atilola ti odo ngbe lo. Ni kia o bo sode, o mu igi gigun kan ti o wa ni ojude re, o si naa si Atilola. Omo na gba igi yi mu dan-in-dan-in bi Ijapa ti faa kuro ninu omi. Bi omo yi ti jajabo, Ijapa mu wo ile re, o da ina fun lati yá, o si fun ni ounjije, sugbon Ijapa ologbon ewe kii sore fun ni laisiregun. O si bere si ronu ohun ti oun le rigba lowo omo na. Ni gẹ́rẹ́ ti omo na jeun tan, o mu orin b’enu o si bere si korin eleyi ti Ijapa ko gbo. Ohun omo na dun gbo leti, o je orin olohun gooro; orin ti iya Atilola ma a nko fun. Orin na lo bayi pe,

‘Omo o, e ii pe dagba

Omo o, e ii pe dagba

Omo o….

Bi omo na ti korin tan, omo na sun. Ijapa si nronu pe, ‘kini mo le se?’ Ijapa si lo sibi ti omo na sun si, o bere si lu ilu nla kan. Nigbati o di ojo keji ti omo na ji, Ijapa pe e o ni ki o joko sinu ilu na. Omo na dahun pe, ‘eese ti emi o fi joko sinu ile?’ Ijapa ni, pelu oore nla nla ti mo se ti mo gba o lowo iku, se o ye ki o ma a bimi nibeere- kibeere. Oya wonu ilu lo. Mo fe dan an wo, bi ohun ilu na se je ni.

Omo yi wonu ilu o joko, Ijapa si mu awo ilu o fi bo ilu, o wa so fun omo na pe, bi mo ba ti fi owo gba ilu ki o bere si korin pe,

‘Omo o, e ii pe dagba..’

Ijapa gbe ilu na, o ta kan, o di ojude laarin oja.

Ni ilu yi, iya ati baba re ti bere si wa. Okan won poruuru, nitori omo na ko pada wale nigbati ojo da. Won wa tititi won ko ri. Won wa rin lo saafin won so f’oba pe omo awon ti sonu, won ko ri.

Bayi ni oba ran awon onise oba lati wa. Won wa gbogbo afonifoji, won ko ri. Nitorina won pada lo jabo f’oba wipe awon ko ri.

Ijapa ko mo pe won nwa omo yi. Sugbon o bo si aarin oja o ni,

‘E wa wo ilu ti nkorin, ilu àràmondà

‘E wa wo ilu ti nkorin, ilu aramonda

‘E wa wo ilu yi o, aramonda ni.

Nigbati awon eeyan pejo, ijapa gbáá ilu, omo na si bere si korin pe:

‘Omo o, e i pẹ́ dagba,

Omo o, eii pẹ́ dagba,

Bayi lomo na bere si korin lohun gooro, ohun re si dun lopolopo. Awon eeyan si bẹ̀rẹ̀ si jo, won nso gele ati fila won sile. Won jo jo jo titi o fi rẹ̀ won, won da owo sile, won si fun ijapa ni owo goboi nitori ilu alaramonda yi.

Ni ojo keji oba ranse pe ijapa, o ni ko wa pelu ilu re si aafin oun. Nigbati ijapa de ‘be, enu ya a lati ria won opolopo eeyan ti won ti joko. Inu re si dun lopolopo, o so fun oba pe, ‘ki emi to lu ilu mi, eyin ni lati fun mi ni owo o’. Oba ko gbo iru oro bayi ri, o se iyalenu fun, sugbon nitori ti o fe gbo ilu ti o ti gburo re, o fun ni apo owo kan. Ijapa si bere si se ise re, o gba ilu yi lori mole, omo na bere si kori pe,

‘Omo o, e i pe dagba,’

O nkorin na, gbogbo eeyan sib ere si jo. Oba dide ati awon ijoye re, bere si jo. Won jo, jo, jo, titi o fi re won. Bi oba tin jo ni o sakiyesi iya Atilola to joko si koro ti o nsokun. Inu bi oba, nitori ko si eniti nsokun niwaju oba. O ni, ki won lo pe iya Atilola ati baba re ti won joko si koro wa siwaju oun. Nigbati won de ọ̀dọ̀ oba, iya Atilola bere si sokun o sope ‘Kabiyesi, oba, ilu ti Ijapa nlu ki iise abami rara, omo mi ni o nkorin ninu ilu yi, ko si iya na ti yio gbo igbe omo re ti ko ni teti si. Bayi ni oba pase ko onikaluku joko jee. O sip e Ijapa o bii wipe, abami ni ilu yi? Ijapa ni beeni. Sugbon arabirin yi ni omo oun ni o nkorin ninu ilu yi. Ijapa ko mo ohun to le so. Oba pase pe ki won fa ori ilu na ya. Bi won ti fa ori ilu na ya ni Atilola ba rora jade jẹ́jẹ́ kuro ninu ilu. Bi o ti ria won obi re ni o sare lo bawon ti o fo mo won lorun ti o si bere si sokun. Inu oba baje lopolopo o so fun Ijapa pe o gbe omo olomo sinu ilu, o si wa nfi pa owo. Oba pase pe ki won lo ti Ijapa sewon, sugbon bi awon emeso ti fe gbe Ijapa, beeni Ijapa wipe ‘e duro na, mo ni oro ti mo fe so’. O koju si oba o ni, ‘Kabiyesi, oba. Emi kini yi lo gba omo yi nigbati ágbàrá òjò ngbe lo. Emi ko ro pee won lo yemi o. Oba ronu titi si oro ti Ijapa so yi. O ni, o daa emi o tu o sile, sugbon mo fe se ikilo yi fun gbogbo eniyan. A ko gbodo ri enikeni ko tun dan ohun buburu yi wo mo, lae ati laelae. Ijapa, emi o tu ọ sile, sugbon o ni lati gbe apo owo ti mo fun o pada. Ijapa gbe apo owo na jade, o si gbe pada fun oba. Lati ojo na lo, Atilola ko eko kan pataki pe, o se pataki ki awon omode ma a gboran si iya won lenu. O se pataki fun awon omode lati ma a gboran si awon obi won lenu.

Nitori eko ti Atilola ti ko yi, o mu eko na lo, o si di akikanju okunrin.

Enjoyed this story?
Find out more here