KidsOut World Stories

Erékùṣù Òòrùn David Heathfield    
Previous page
Next page

Erékùṣù Òòrùn

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

Erékùṣù Òòrùn

Ìtàn Àwọn Ara Ṣáínà Kan

 

a blue bird and a red bird in a circle

 

 

 

 

 

*

Àgbẹ̀ kan wà tó ní àwọn ọmọkùnrin méjì.

Èyí àgbà ọkùnrin jẹ́ amọtaraẹninìkan àti olójúkòkòrò, nígbàtí èyí àbúrò jẹ́ onínúure àti ẹni tó lawọ́.

Nígbàtí àgbẹ̀ náà kú, àgbà ọkùnrin náà gba gbogbo ilẹ̀ bàbá rẹ̀ fún ara rẹ̀ láì fún àbúrò rẹ̀ ní ohunkóhun yàtọ̀ sí apẹ̀rẹ̀ kan àti ọ̀bẹ tó lè fi gé igi ìdáná.

Yóò lọ sínú igbó, yóò sì gé igi láti tà fún pàṣípààrọ̀ ìrẹsì kékeré díẹ̀ ní ọjà.

Tálákà ni. Kò ní ohunkóhun.

Ní ọjọ́ kan, àbúrò náà gun àwọn òkè ńlá la igbó kọjá títí tó fi dé orí àpáta kan. Ó jókòó sórí àpáta kan, ó kọjú sí ìwọ̀-òòrùn, ó ń wo bí òòrùn ṣe ń wọ̀.

Bí o ti jókòó ní òun nìkan, afẹ́fẹ́ kan fẹ́ lùú láti òkè wá, ó wòkè, ó sì rí ẹyẹ aláwọ̀ títàn kan tó ń fò bọ̀ lọ́dọ̀ rẹ̀. Ìyẹ́ rẹ̀ tóbi púpọ̀.

Ó ń gbọ́ bí ó ṣe ń fi ìyẹ́ rẹ̀ lu afẹ́fẹ́, bí afẹ́fẹ́ ṣe ń fẹ́ kíkankíkan. Ẹyẹ náà bà sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

‘Ki lo dá jókòó síbí fún?’

‘Tálákà ni mí. Èmi kò ní ohunkóhun.’

‘Ṣé lóòótọ́ tàbí irọ́?’

‘Òótọ́ ni, tálákà ni mí. Èmi kò ní ohunkóhun.’

‘Pọ́n sẹ́yìn mi nígbà náà,’ ẹyẹ ńlá náà fèsì, ‘èmi yóò sì gbé ọ lọ sí Erékùṣù Òòrùn.

Níbẹ̀, o lè mú ẹyọ wúrà kan kí n tó gbé ọ padà wá.’

Ó pọ̀n sẹ́yìn ẹyẹ náà, ẹyẹ náà sì ń fò lọ.

Ẹyẹ ńlá náà fò lọ kúrò nítòsí àpáta náà.

Ẹyẹ ńlá náà fò kọjá lórí igbó ńlá náà.

Ẹyẹ ńlá náà fò kọjá lórí àwọn omi ńlá.

Ẹyẹ ńlá náà fò lọ sí Erékùṣù Òòrùn.

Bí ẹyẹ náà ṣe ń bà sórí ilẹ̀, òòrùn tó ń wọ̀ lẹ́yìn erékùṣù náà ń tàn mọ́lẹ̀, ọmọkùnrin náà sì mú ẹyọ wúrà kan.

Ó fi sínú apẹ̀rẹ̀ rẹ̀, ó sì pọ̀n sẹ́yìn ẹyẹ ńlá náà padà.

Ẹyẹ ńlá náà fò lọ kúrò nítòsí erékùṣù náà.

Ẹyẹ ńlá náà fò kọjá lórí àwọn omi ńlá.

Ẹyẹ ńlá náà fò kọjá lórí igbó ńlá náà.

Ẹyẹ ńlá náà fò padà lọ sórí àpáta náà.

Àbúrò náà mú ẹyọ wúrà náà, ó sọ̀kalẹ̀ jáde kúrò nínú igbó náà, ó sì lọ ra ilẹ̀ kékeré kan síbẹ̀.

Níbẹ̀, ó ń sin ẹlẹ́dẹ̀, máàlù, àti adìẹ mélòó kan.

Ó ń gbé ayé tó dára. Ó ń ṣíṣẹ́ takun-takun.

Ṣùgbọ́n ní ọjọ́ kan ẹ̀gbọ́n rẹ̀ wá.

‘Ibo ni o ti rí ọrọ̀ tó pọ̀ tó èyí, ilẹ̀ yìí?’

Àbúrò rẹ̀ sọ fún un bó ṣe jẹ́.

‘Èmi náà fẹ́ irú rẹ̀. Fún mi ní apẹ̀rẹ̀ àtijọ́ yẹn àti ọ̀bẹ rẹ.’

Ẹ̀gbọ́n náà gba ọ̀nà igbó lọ. Nígbàtí ó dé ibití àwọn òkè náà wà, ó jókòó sórí àpáta kan, ó ń dúró.

Nígbàtí ó pẹ́ díẹ̀, afẹ́fẹ́ kan fẹ́ lùú, ó sì gbúròó àwọn ìyẹ́ tó ń dún.

Níbẹ̀, bí ó ṣe kọjú sí ìwọ̀-òòrùn, tí ó ń wo bí òòrùn ṣe ń wọ̀, ẹyẹ kan farahàn láti inú títàn òòrùn náà, ó ń fi ìyẹ́ rẹ̀ lu afẹ́fẹ́, ó ń súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀.

Ẹyẹ náà sì bà sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

‘Ki lo dá jókòó síbí fún?’

‘Tálákà ni mí. Èmi kò ní ohunkóhun.’

‘Ṣé lóòótọ́ tàbí irọ́?’

‘Òótọ́ ni, tálákà ni mí. Èmi kò ní ohunkóhun. Mo fẹ́ wúrà!’

‘Pọ̀n sí mi lẹ́yìn,’ ẹyẹ ńlá náà wí. ‘Èmi yóò gbé ọ lọ sí Erékùṣù Òòrùn. Níbẹ̀, o lè mú ẹyọ wúrà kan.’

Ẹyẹ ńlá náà fò lọ kúrò nítòsí àpáta náà.

Ẹyẹ ńlá náà fò kọjá lórí igbó ńlá náà.

Ẹyẹ ńlá náà fò kọjá lórí àwọn omi ńlá.

Ẹyẹ ńlá náà fò lọ sí Erékùṣù Òòrùn.

Bí ó ṣe bà sórí ilẹ̀, òòrùn tó ń wọ̀ lẹ́yìn erékùṣù náà ń tàn mọ́lẹ̀.

Ẹ̀gbọ́n náà wo ilẹ̀, ó rí wúrà tó ń dán káàkiri ibi gbogbo. Ó mú ẹyọ ọ̀kan, ó fi sínú apẹ̀rẹ̀.

‘Apẹ̀rẹ̀ náà dàbí èyí tó ṣófo. Yóò dára kí n mú òmíràn.’

Ó mú ẹyọ kejì sínú apẹ̀rẹ̀ náà, lẹ́yìn náà ẹyọ kẹta.

Ó tẹ̀síwájú láti máa kó àwọn wúrà tó tóbi jùlọ níbẹ̀ títí tí apẹ̀rẹ̀ náà fi kún dẹ́mú.

Ó yípadà. Bí ó ṣe yípadà, ó ríi pé ẹyẹ náà ti fò lọ, òòrùn sí ti ń ràn. Kò lè lọ síbikíbi mọ́.

Àbúrò náà jogún ilẹ̀ ẹ̀gbọ́n rẹ̀. Ó ṣètọ́jú ilẹ̀ náà dáradára pẹ̀lú ìfẹ́.

Ohun tó ń rí láti orí rẹ ni òun máa ń ṣàjọpín pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn ní àwùjọ náà.

Enjoyed this story?
Find out more here