KidsOut World Stories

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ Aláàrékérekè àti àwọn Ẹ̀tàn rẹ̀    
Previous page
Next page

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ Aláàrékérekè àti àwọn Ẹ̀tàn rẹ̀

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ Aláàrékérekè

àti àwọn Ẹ̀tàn rẹ̀

 

 

 

 

 

 

 

 

 

 

Nígbà kan rí, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kan wà, aláàrékérekè bí àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ṣe máa ń rí. Ó ti ń lọ kiri láti wá oúnjẹ jálẹ̀ alẹ́ ọjọ́ náà, kò sì rí oúnjẹ kankan rárá. Nígbàtí ilẹ̀ mọ́, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà rá lọ sí ẹ̀gbẹ́ẹ títì, ó sì sá sábẹ́ igbó. Ó ń ronú ohun tó kù láti ṣe kí òun lè rí nǹkan kan jẹ.

Bí ó ti sùn síbẹ̀ pẹ̀lú orí rẹ̀ lórí ẹsẹ̀ rẹ̀, ó gbóòórùn ẹja. Ó gbé orí sókè díẹ̀. Ó bojúwo ojú-ọ̀nà náà látòkè dé ilẹ̀, ó sì rí kẹ̀kẹ́-akẹ́rù kan tí àwọn máàlù méjì kan ń fà bọ̀.

“Ó dára,” kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà wí nínú ọkàn ara rẹ̀. “Oúnjẹ tí mo ti ń dúró dé nìyí.”

Láì fi àsìkò ṣòfò, ó sáré jáde láti abẹ́ igbó. Ó sùn sílẹ̀ laarin ọ̀nà bí ẹni tó ti kú.

Bí kẹ̀kẹ́-akẹ́rù náà ṣe ń súnmọ́ ibití kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà wà, arákùnrin tó ń waá ríi. Pẹ̀lú èrò pé ó ti kú lótìítọ́, ó kígbe láti dá àwọn máàlù náà dúró. “Whoa! Whoa!”

Àwọn máàlù náà dúró. Arákùnrin náà súnmọ́ kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà, ó sì wòó dáradára. Ó ríi pé kò mí mọ́.

“Ó máṣe o!” ó wí. “Báwo ni kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ yìí ṣe kú síbí? Aṣọ àwọ̀sókè tó dára tí èmi yóò rán fún aya mi pẹ̀lú irun ara rẹ̀ yóò yanilẹ́nu!”

Bí ó ṣe sọ èyí, ó gbé kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà sókè láti ẹ̀yìn ọrùn rẹ̀. Ó wọ́ọ lọ síbí kẹ̀kẹ́-akẹ́rù náà, ó sì gbée sínú rẹ̀, lórí àwọn ẹja tó wà níbẹ̀.

Lẹ́yìn náà, arákùnrin náà ní kí àwọn màálù náà máa tẹ̀síwájú. “Gbéranílẹ̀, Joian! Gbéranílẹ̀, Bourean!”

Àwọn màálù náà bẹ̀rẹ̀ síí kilẹ̀ lọ síwájú. Arákùnrin náà rìn kọjá lára àwọn màálù náà, ó ń fi igi kan gún wọ́n lára láti mú wọn rìn kíákíá. Ó ń fẹ́ láti tètè dé ilé láti yọ awọ ara kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà.

Bí àwọn màálù náà ṣe ń kilẹ̀ lọ, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà ń fi ẹsẹ̀ rẹ̀ ti àwọn ẹja náà bọ́ sílẹ̀ kúrò nínú kẹ̀kẹ́-akẹ́rù náà. Arákùnrin náà ń fi igi gún àwọn màálù lára, kẹ̀kẹ́-akẹ́rù náà ń pariwo, ẹja sì ń jábọ́ sílẹ̀ lẹ́yìn.

Nígbàtí ó ti tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja jábọ́, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà fò jáde láti lọ kó wọn jọ pọ̀ kúrò lójú ọ̀nà. Nígbàtí ó ti kó gbogbo ẹja náà jọ papọ̀ tán, ó kó wọn lọ sínú ihò rẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ síí jẹ wọ́n. Ebi ti paá púpọ̀!

Kò pẹ́ tí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí jẹun ni ó gbàlejò àìròtẹ́lẹ̀ kan, ẹranko beari.

“Mo bá ọ re, ọ̀rẹ́ mi. Ó ga o! Ẹja ló pọ̀ tó yìí! Ṣe èmi náà lè rí lára rẹ̀ bí? Ebi ẹja ń pa mí!” beari náà ń bẹ̀bẹ̀.

“Wòó, kí ebi náà yára máa pa ọ́ lọ, ọ̀rẹ́ mi. Èmi kìí ṣiṣẹ́ fún ẹlòmíràn láti jẹ. Bí ebi ẹja bá kúkú ń pa ọ́ tó yẹn, lọ ki ìrù rẹ bọ inú odò bí èmi náà ti ṣe. Ìwọ náà á tó ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja láti jẹ,” kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà fèsì.

“Kọ́ mi bí a ṣe ń ṣeé nígbà náà,” ni beari náà wí. “Èmi kò mọ bí a ṣe lè mú ẹja lódò.”

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà rẹ́rìn-ín, ó wí pé, “Ṣé lóòtọ́, ọ̀rẹ́ mi? Ṣùgbọ́n ṣé o kò mọ̀ pé àìnírètí a máa mú ni lọ síbití ènìyàn kò fẹ́ lọ, a sì máa kọ́ni ní àwọn ohun tí ènìyàn kò lè rò bí? Lọ sínú odò tó wà létí igbó lálẹ́ òní. Ki irú rẹ sínú omi náà, kí o sì jókòó láì mira títí ilẹ̀ yóò fi fẹ́rẹ̀ẹ́ mọ́. Bí òòrùn bá ti bẹ̀rẹ̀ síí ràn, gbéranílẹ̀ bí ẹni tó fẹ́ máa lọ sétí omi náà. Ìwọ yóò kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹja jáde, bóyá ìlọ́pọ méjì tàbí mẹ́ta iye tí èmi kó.”

Láì sọ ohunkóhun, ẹranko beari náà sáré lọ sínú odò tó wà létí igbó náà. Ó ki ìrù ara rẹ̀ sínú odò, ó sì jókòó jẹ́ẹ́.

Ní òru ọjọ́ náà, ìjì líle kan bẹ̀rẹ̀ sí fẹ́. Ó burú dé ibi pé ó lè sọ ahọ́n ènìyàn di yìnyín dídì nínú ẹnu ẹni. Omi inú odò náà dì bí òkúta, ó sì mú ìrù beari náà mọ́lẹ̀. Nígbàtí ó pẹ́ díẹ̀, ti beari náà kò lè farada ìrora náà mọ́, ó fa ara rẹ̀ yọ pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀. Ó sì ṣe lára beari aláìgbọ́n náà, nítorí kàkà kí ó rí ẹja púpọ̀ kó, ńṣe ni ó di ẹranko aláìnírùmọ́!

Ó kérora púpọ̀, ó sì fò sókè àti sílẹ̀ pẹ̀lú ìrora. Pẹ̀lú ìbínú sí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà pé ó tan òun jẹ, beari náà gba ihò kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà lọ.

Ṣùgbọ́n ṣá, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ aláàrékérekè náà mọ bí ó ṣe lè fi ara rẹ̀ pamọ́ lọ́wọ́ ìbínú beari náà. Nígbàtí ó rí beari náà tó ń bọ̀ láìní ìrù mọ́, ó sálọ kúrò nínú ihò rẹ̀, ó sì farapamọ́ saarin igi oníhò kan nítosí.

“Pẹ̀lẹ́ o, ọ̀rẹ́ mi!” kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà ń kíi. “Ṣe ẹja ni ó jẹ ìrù rẹ ni, tàbí ojúkòkòrò rẹ ló pọ̀ dé ibi pé o kò lè ṣẹ́ ẹja kankan kù sínú omi?”

Nígbàtí ó gbọ́ pé kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà ń fi òun ṣe yẹ̀yẹ́, ó sáré lọ sí ìdí igi náà. Ṣùgbọ́n ẹnu ihò náà kéré púpọ̀, beari náà kò sì lè wọ inú rẹ̀. Ó wá ẹ̀ka igi kan tó ṣẹ́po díẹ̀ tó ní ẹnu tó dàbí ìwọ̀. Beari náà bẹ̀rẹ sí fi ìwọ̀ náà wá kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà kiri nínú ihò náà láti wọ́ kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà jáde.

Nígbà yòówù tó bá mú ẹsẹ̀ rẹ̀ kan, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà yóò kígbe pé: “Máa fàá, ìwọ ọ̀dẹ̀ yìí! Igi lò ń fà; èwo ló wá kàn mí?”

Nígbà yòówù tí ìwọ̀ náà bá mú igi, yóò kígbe: “Yéè, ọ̀rẹ́ mi! Má fàá mọ́; o ti fẹ́ fa ẹsẹ̀ mi já!”

Beari náà gbìyànjú títí, ṣùgbọ́n kò lè dé ibití kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà wà.

Níkẹyín, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà tòògbé pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn, nítorí tí ó lo ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀, kìí ṣe fún arákùnrin oníkẹ̀kẹ́ náà nìkan, ṣùgbọ́n fún beari náà tí kò bá kó oúnjẹ rẹ̀ lọ pẹ̀lú!

Èyì ni ìtàn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ aláàrékérekè àti àwọn ẹ̀tàn rẹ̀.

Enjoyed this story?
Find out more here