KidsOut World Stories

Àwọn Ọ̀rẹ́ Títí Ayé Farida Salifu    
Previous page
Next page

Àwọn Ọ̀rẹ́ Títí Ayé

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

Àwọn Ọ̀rẹ́ Títí Ayé

Ìtàn Àwọn Akani láti Ghana

 

A frog and a mouse sitting side by side 

 

 

 

 

 

 

 

*

Ẹranko asín àti ọ̀pọ̀lọ́ kan wà nígbà kan rí tí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ gidi. Ní gbogbo òwúrọ̀, ọ̀pọ̀lọ́ náà yóò lọ kí asín náà tó ń gbé nínú ihò kan nínú igi. Asín náà a máa gbádùn bí ọ̀pọ̀lọ́ náà ṣe ń wá kíi, ṣùgbọ́n asín náà kò mọ̀ pé ó ti ń sú ọ̀pọ̀lọ́ náà nítorí pé òun nìkan ni ó máa ń lọ kí asín náà nígbà gbogbo láì jẹ́ pé asín náà wá kíi padà.

Asín ọ̀lẹ kékeré náà kò mọ̀ èyí nígbà náà, ṣùgbọ́n díẹ̀díẹ̀, ó ń sọ ara rẹ̀ di ọ̀tá ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́, ọ̀pọ̀lọ́ náà.

Ní ọ̀sán ọjọ́ kan, nígbàtí ó tó àkókò fún ọ̀pọ̀lọ́ náà láti máa lọ sílé, ó pinnu pé ìbáṣọ̀rẹ́ tó pọ̀ sí ẹ̀gbẹ́ kan náà ti sú òun. Nítorí náà, ọ̀pọ̀lọ́ náà so okùn kan mọ́ ẹsẹ̀ ara rẹ̀, ó sì so ìdàkejì okùn náà mọ́ ìrù asín náà láì jẹ́ kó mọ̀.

Ọ̀pọ̀lọ́ náà juwọ́ sí asín náà pé ó dàbọ̀, ó sì fò sínú omi tó jìnnà réré tó wà nísàlẹ̀ igi náà. Lọ́gán, pẹ̀lú ìyàlẹ́nu fún asín náà, okùn náà fa ìrù rẹ̀ lọ́nà tó le ṣinṣin, ó sì wọ́ọ lọ kúrò lábẹ́ ààbò igi rẹ̀ sínú afẹ́fẹ́ tó gbée lọ sínú odò tó wà nísàlẹ̀ náà. Gbosa!

Asín kékeré aláìgbọ́n náà kò mọ̀ọ́ wẹ̀, bí ó sì ṣe gbìyànjú tó láti tú ìrù ara rẹ̀ sílẹ̀, kò rí okùn náà tú. Nígbàtí ó ti lúwẹ̀ẹ́, tó sì ti tiraka títí, asín náà rì sínú omi odò náà.

‘Èyí yóò kọ́ ọ lọ́gbọ́n láti yéé wò mí bí ọ̀dẹ̀ mọ́, ìwọ ọ̀lẹ asín yìí,’ ni ọ̀pọ̀lọ́ náà ń rò.

Ṣùgbọ́n ìwà ìbàjẹ́ rẹ̀ kò lọ lásán: lókè lójú ọ̀run jìnnà réré, ẹyẹ àṣá kan rí asín kékeré náà tó léfòó sórí omi nísàlẹ̀. Àṣá tí ebi ti pa náà fò wálẹ̀ síbití omi náà wà láti gbé asín kékeré náà jẹ bí oùnjẹ alẹ́.

Ìgbàtí àṣá náà gbá asín náà mú pẹ̀lú àwọn èékánná ṣọ̀bọ̀lọ̀-ṣọ̀bọ̀lọ̀ ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ọ̀pọ̀lọ́ náà tó rántí pé òun ti so ara òun mọ́ asín náà pẹ̀lú okùn.

Òkè, òkè sójú ọ̀run ni ọ̀pọ̀lọ́ náà ń lọ, títí tí àṣá náà fi bà sórí ẹ̀ka tó ga jùlọ lórí igi kan tó wà nítòsí. Ìgbà náà ni ọ̀pọ̀lọ́ náà wá rí àṣìṣe tó wà nínú ìwà rẹ̀. Ní dídẹ pàkúté fún ọ̀rẹ́ rẹ̀, ọ̀pọ̀lọ́ náà dẹ pàkúté fún ara rẹ̀ pẹ̀lú, ó sì yan kádàrá ara tirẹ̀ náà. Nísìnyí, àṣá náà yóò jẹ òun náà nítorí ètò ìkà rẹ̀.

Òwe ilẹ̀ Áfíríkà kan wí pé ... ‘Máṣe gbẹ́ kòtò tó jìnnà púpọ̀ fún ọ̀tá rẹ nítorítí ìwọ fúnraàrẹ pàápàá lè bọ́ sínú rẹ̀.’

Enjoyed this story?
Find out more here