KidsOut World Stories

Ìdí tí Anansi fi ni E̩sẹ̀ Tíírín mẹ́jọ Farida Salifu    
Previous page
Next page

Ìdí tí Anansi fi ni E̩sẹ̀ Tíírín mẹ́jọ

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

Ìdí tí Anansi fi ni E̩sẹ̀ Tíírín mẹ́jọ

Ìtàn Àwo̩n Akani Kan

 

 

 

 

 

 

*

Nígbà kan rí, aláǹtakùn kan tí à ń pè ní Anansi wà. Bí ó tilè̩ jé̩ pé aya Anansi mo̩ o̩bè̩ sè dáradára, olójúkòkòrò aláǹtakùn náà kò fé̩ràn ohun mìíràn ju pé kó máa tó̩ oúnje̩ àwo̩n e̩lòmíràn wò lo̩.

Ní o̩jó̩ kan, Anansi yà láti lo̩ kí ò̩ré̩ rè̩, ehoro. 

‘Hmm!’ aláǹtakùn olójúkòkòrò náà pariwo bí ó s̩e ń wo̩ yàrá ìdáná. ‘Ewébè̩ tó dára ni ìwo̩ ń sè yìí o, Ehoro.’ 

‘Kò ha dára kí ìwo̩ kúkú dúró fún oúnje̩ alé̩ bí?’ ehoro onínúure náà fèsì. ‘Àwo̩n ewébè̩ náà kò tíì jinná tán, s̩ùgó̩n wo̩n yóò tó jinná.’

Anansi mò̩ pé bí òun bá dúró nígbàtí oúnje̩ náà s̩ì ń sè ló̩wó̩, ehoro náà yóò máa rán òun nís̩é̩ dájúdájú, aláǹtakùn olójúkòkòrò náà kò sì wá kí ò̩ré̩ rè̩ láti wá s̩is̩é̩.

Nítorí náà, Anansi wí fún ehoro náà pé,

‘Jò̩wó̩ foríjì mi, ò̩ré̩ mi ò̩wó̩n, s̩ùgbó̩n mo ní àwo̩n ohun kan tí mo ní láti s̩e ní báyìí. Ìwo̩ kò s̩e jé̩ kí ń so ìwò̩n ìtàkùn mi kan mó̩ e̩sè̩ mi, kí ń sì so e̩nu ìtàkùn náà kejì mó̩ ara ìkòkò o̩bè̩ re̩? Nípa bé̩è̩ ìwo̩ yóò lè fa ìtàkùn náà nígbàtí ewébè̩ náà bá jinná, èmi yóò sì sáré padà wá fún oúnje̩ alé̩.’

Ehoro náà gbà pé èyí jé̩ èrò tó dára, nítorí náà, ó so ìtàkùn Anansi mó̩ ìkòkò rè̩, ó sì juwó̩ síi pé ó dàbò̩.

Láìpé̩, aláǹtakùn olójúkòkòrò náà bá ara rè̩ bó s̩e ń rìn lo̩ nítòsí ilé ò̩ré̩ rè̩ tímó̩timó̩, ò̩bo̩. Ó sì wá s̩e̩lè̩ pé Ò̩bo̩ náà ń se oúnje̩ alé̩ tirè̩ ló̩wó̩ nígbà náà.

‘Hmm!’ aláǹtakùn olójúkòkòrò náà pariwo bí ó s̩e ń wo̩ yàrá ìdáná. ‘Àpapò̩ è̩wà àti oyin tí ìwo̩ ń sè yìí má dára púpò̩ o, Ò̩bo̩.’

‘Ìwo̩ kò ha s̩e dúró kí wó̩n jinná kí o lè je̩ oúnje̩ alé̩ níbí?’ ò̩bo̩ onínúure náà fèsì.

Lé̩è̩kansíi, Anansi mò̩ pé bí òun bá dúró nígbàtí oúnje̩ náà s̩ì ń sè ló̩wó̩, Ò̩bo̩ náà yóò máa rán òun nís̩é̩ dájúdájú, aláǹtakùn olójúkòkòrò náà kò sì fé̩ láti s̩is̩é̩ kankan rárá.

Nítorí náà, Anansi wí fún Ò̩bo̩ náà pé,

‘Jò̩wó̩ foríjì mi, ò̩ré̩ mi ò̩wó̩n, s̩ùgbó̩n mo ní àwo̩n ohun kan tí mo ní láti s̩e ní báyìí. Ìwo̩ kò s̩e jé̩ kí ń so ìwò̩n ìtàkùn mi kan mó̩ e̩sè̩ mi, kí ń sì so e̩nu ìtàkùn náà kejì mó̩ ara ìkòkò o̩bè̩ re̩? Nípa bé̩è̩ ìwo̩ yóò lè fa ìtàkùn náà nígbàtí è̩wà àti oyin náà bá jinná, èmi yóò sì sáré padà wá fún oúnje̩ alé̩.’

Ò̩bo̩ náà gbà pé èyí jé̩ èrò tó dára púpò̩, nítorí náà, ó so ìtàkùn Anansi mó̩ ìkòkò rè̩, ó sì juwó̩ síi pé ó dàbò̩.

*

Ní ọ̀nà ilé rè̩, Anansi lo̩ kí awo̩n ò̩ré̩ rè̩ mé̩fà mìíràn, gbogbo wo̩n sì ń se oúnje̩ alé̩ wo̩n ló̩wó̩.

Ó lo̩ sí ilé ìjàpá, ehoro, ò̩ké̩ré̩, asín, kò̩lò̩kò̩lò̩, àti níke̩yìn, ó lo̩ ki ò̩ré̩ rè̩ tímó̩timó̩, e̩lé̩dè̩-igbó.

Bé̩è̩ sì ni, ní ibìkàn-àn-kan tó lo̩, Anansi lo ìtàn àtijó̩ rè̩ kan náà. Fún ò̩ré̩ kò̩ò̩kan, ó so ìwò̩n ìtàkùn rè̩ kan mó̩ ìkòkò o̩bè̩ wo̩n.

Bé̩è̩ ló sì s̩e s̩e̩lè̩ pé gbogbo e̩sè̩ Anansi mé̩jè̩è̩jo̩ ni ó so mó̩ ìkòkò o̩bè̩ orís̩irís̩i nípasè̩ àwo̩n ìwò̩n ìtàkùn gígùn.

Aláǹtakùn olójúkòkòrò náà kò lè s̩àì tan ò̩kò̩ò̩kan àwo̩n ò̩ré̩ rè̩ je̩ kí ó bá a lè je̩ lára ohun tó wà nínú ìkòkò wo̩n, s̩ùgbó̩n kí ó más̩e bá wo̩n s̩is̩é̩ kankan rárá.

Anansi ní ìrètí ńlá láti je̩ gbogbo àwo̩n oúnje̩ náà, pàápàá jùlo̩ àpapò̩ is̩u àti oyin e̩lé̩dè̩-igbó, èyítí ó mò̩ó̩ sè dáradára.

‘Mo ti s̩e ohun tó ko̩já agbára mi ló̩tè̩ yìí,’ aláǹtakùn olójúkòkòrò náà rò nínú ara rè̩. ‘Ò̩pò̩ oùnje̩ tó dára fún jíje̩, mo tilè̩ tún yó̩ gbogbo is̩é̩ sílè̩ pàápàá! A kò tilè̩ mo̩ ìkòkò oúnje̩ wo ni yóò kó̩kó̩ jinná pàápàá?’

*

Ní àsìkò náà, Anansi ríi tí wó̩n ti ń fa ìtàkùn e̩sè̩ òun kan.

‘Ó ń láti jé̩ ehoro-onírun nìye̩n pè̩lú o̩bè̩ ewébè̩ aládùn rè̩,’ aláǹtakùn olójúkòkòrò náà rò nínú ara rè̩.

S̩ùgbó̩n nígbà náà, ìtàkùn mìíràn tún bè̩rè̩ sí fa e̩sè̩ Anansi.

‘Orí mi ò!’ ó pariwo síta. ‘Ó ń láti jé̩ ò̩bo̩ nìye̩n pè̩lú ìkòkò è̩wà àti oyin rè̩.’

Wó̩n tún ń fàá ní e̩sè̩ mìíràn! Àti òmíràn! Àti òmíràn! Títí wó̩n fi ń fa e̩sè̩ Anansi mé̩jè̩è̩jo̩ lórís̩irís̩i ò̩nà lé̩è̩kan náà!

Anansi wó̩ ara rè̩ lo̩ sí ìdí odò, ó fò sínú omi náà kí ó lè fo̩ gbogbo ìtàkùn e̩sè̩ rè̩ dànù.

Ló̩kò̩ò̩kan, àwo̩n ìtàkùn náà tú kúrò lé̩sè̩ rè̩ títí tí aláǹtakùn olójúkòkòrò náà fi lè gùnkè padà sí etí odò náà níke̩yìn.

Nígbàti Anansi ti bó̩ nínú wàhálà yìí, tí ó sì gbìyànjú láti mú kí ara rẹ̀ lè gbe̩, ó s̩àkíyèsi ohun kan tó s̩àjèjì.

Ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́jẹ̀ẹ̀jọ ló ti gùn síi.

Níbi tó ti jẹ́ pé wọ́n ti kúrú té̩lè̩rí, tí wọ́n sì fẹ́, nísìnyí wọ́n ti tíírín, wọ́n sì gùn!


‘Yéèèè kí ló wá ṣe mí tí mo fi jẹ́ irú olójúkòkòrò bí èyí?’ Anansi ronú. ‘Nísìnyí, wo ohun tí mo wá dì. Kìí ṣe pé mo ní ẹsẹ̀ tíírín mẹ́jọ nìkan, ṣùgbọ́n nísìnyí, mo tún gbọ́dọ̀ máa se oúnjẹ alẹ́ mi fúnraara mi!’

Ìdí nìyí tí Anansi fi ni ẹsẹ̀ tíírín mẹ́jọ.

Enjoyed this story?
Find out more here