KidsOut World Stories

Funfun Láú    
Previous page
Next page

Funfun Láú

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

Funfun Láú

 

 

 

 

 

 

 

 

 

*

Ní ìgbà òtútù kan, nígbàtí yìnyín ń dà bí ìyẹ́ láti ojú ọ̀run, ayaba kan ń fẹ́ láti bí ọmọbìnrin. Láìpẹ́, àníyàn rẹ̀ ṣẹ nítòótọ́.

Wọ́n pe orúkọ ọmọ náà ní Funfun Láú nítorí ara rẹ̀ fúnfún bí ẹgbọ̀n òwú. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ pupa bí ẹ̀jẹ̀. Irun orí rẹ̀ dúdú bí kóró iṣin.

Láìpẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí a bí Funfun Láú, ìyá rẹ̀ kú.

Lẹ́yìn tí ọdún kan ti kọjá, ọba ìlú náà tún ṣe ìgbéyàwò. Ayaba tuntun náà rẹwà púpọ̀. Ó ní dígí onídán kan. Bí ó bá ti wo ara rẹ̀ nínú dígí náà, yóò bèrè pé:

‘Dígí, dígí ara ògiri,
Ta ló rẹwà jùlọ nínú gbogbo ènìyàn?’

Dígí náà dáhùn:

‘Ìwọ ló rẹwà jùlọ nínú gbogbo ènìyàn.’

Inú ayaba náà yóò sì dùn. Ó mọ̀ pé dígí náà a máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo.

Ṣùgbọ́n, lójoojúmọ́, Funfun Láú ń dàgbà díẹ̀díẹ̀. Ọmọdé tó rẹwà ni, ó sì dàgbà di arẹwà obìnrin. Ọmọba wá di arẹwà tó rẹwà ju ayaba lọ.

Nítorí náà, ní ọjọ́ kan, nígbàtí ayaba bèèrè ìbéèrè rẹ̀ lọ́wọ́ dígí náà, ó fèsì:

‘Arábìnrin Mi, ìwọ rẹwà lótìítọ́,
Ṣùgbọ́n Funfun Láú rẹwà jù ọ́ lọ.’

Ojú ayaba yípadà. Láti ìgbà náà lọ, ó kórira Funfun Láú bíi májèlé. Ojoojúmọ́ ni inú ń bíi síi. Láti máa jowú ènìyàn dàbí gbígbin igi oró sínú ọkàn ẹni. Níkẹyìn, wọn a máa dàgbà láti lágbára púpọ̀, wọn a sì há ni lọ́fun pa.

Níkẹyìn, ayaba kò lè mú rírí Funfun Láú lójoojúmọ́ mọ́ra mọ́. Nítorí náà, ó pàṣẹ pé kí alénipa rẹ̀ ṣe ohun búburú kan.

‘Mú Funfun Láú lọ sínú igbó. Èmi kò fẹ́ rí ojú rẹ̀ mọ́ láíláí. O gbọ́dọ̀ paá. Mú ìfun àti ẹ̀dọ̀ rẹ̀ padà wá fún mi, kí ń lè fi mọ̀ pé ó ti kú.’

Alénipa náà gbìyànjú láti ṣe bí a ti rán-an. Ó mú Funfun Láú lọ sínú igbó. Ó tilẹ̀ yọ ọ̀bẹ rẹ̀ jáde láti paá.

Funfun Láú kígbe síta. ‘Yéèèè! Jọ̀wọ́ máṣe pa mi lára. Mo ṣèlérí pé bí o bá lè tú mi sílẹ̀, èmi yóò sálọ sínú igbó, èmi kì yóò sì padà sílé mọ́ láíláí.’

‘Ó dára, máa sálọ nígbà náà,’ ó fèsì, nítorí tí àánú rẹ̀ ṣeé. Ọkàn rẹ̀ di fífúyẹ́ nítorí tí kò ṣe ohun búburú náà.

Bí alénipa náà ṣe ń lọ laarin igbó, ẹranko ìmàdò kékeré kan sáré kọjá níwájú rẹ̀. Ó yìnbọn fún un, ó sì mú ìfun àti ẹ̀dọ̀ rẹ̀ padà lọ fún ayaba láti fihàn pé Funfun Láú ti kú. Ayaba búburú náà jẹ́ kí wọ́n fi se ọbẹ̀, ó sì jẹẹ́. Ó lérò pé òun ti rẹ́yìn Funfun Láú.

Nígbàtí Funfun Láú bá ara rẹ̀ nínú igbó, àwọn igi tó yíiká dàbíi nǹkan mìíràn. Ẹ̀rú bàá dé ibi pé kò mọ ohun tó lè ṣe. Pẹ̀lú ìbẹ̀rù-bojo, ó bẹ̀rẹ̀ sí sáré lọ lórí àwọn òkúta mímú laarin igbó náà. Àwọn ẹranko tó burú jùlọ nínú igbó sáré kọjá rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò paá lára.

Funfun Láú sáré wọ inú igbó náà bí agbára àti ẹsẹ̀ rẹ̀ ti fún un láàyè tó. Bí ọjú-ọ̀run ṣe bẹ̀rẹ̀ sí dúdú, ó rí ilé kékeré kan, ó sì wọlé sí ibẹ́.

Ohun gbogbo tó wà níbẹ̀ ló kéré. Tábìlì kan wà pẹ̀lú àwọn abọ́ kékèké méje lórí rẹ̀, ọ̀kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú amúga ìjẹun, ọ̀bẹ àti ṣíbí kékèké. Ife ìmumi méje kékèké náà wà lórí rẹ̀. Ibùsùn kékèké méje náà tún wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ògiri.

Ebi ń pa Funfun Láù, òrùngbẹ sì ń gbẹẹ́ dé ibi pé ó jẹ díẹ̀ lára oúnjẹ tó wà nínú abọ́ kọ̀ọ̀kan, ó sì mu díẹ̀ lára omi tó wà nínú ife ìmumi kọ̀ọ̀kan. Lẹ́yìn náà, ó dùbúlẹ̀ sórí ọ̀kan lára àwọn ibùsùn náà, ó sì sùn lọ.

Nígbàtí òkùnkùn àṣálẹ́ náà ti ṣú bolẹ̀ gidi, àwọn tó ni ilé kékeré náà padà sílé wọn. Ràrá méje ni wọ́n, wọ́n sì ti jáde lọ láti ṣiṣẹ́ takun-takun látàárọ̀. Wọ́n ń ṣiṣẹ́ ní ibití wọ́n ti ń la òkúta, lọ́nà jíjìn laarin àwọn àpáta.

Àwọn ràrá náà tan àtùpà méje, wọ́n sì wò káàkiri inú yàrá náà. Wọ́n mọ̀ pé ẹnìkan ti wọ inú ilé àwọn.

Ìkínní wí pé, ‘Taló ti jókòó sórí àga mi?’

Ìkejì wí pé, ‘Taló jẹ àkàrà mi?’

Ìkẹta wí pé, ‘Taló jẹ àsáró mi?’

Ìkẹrin wí pé, ‘Taló jẹ ẹ̀fọ́ mi?’

Ìkarùn-ún wí pé, ‘Taló lo amúga ìjẹun mi?’

Ìkẹfà wí pé, ‘Taló fi ọ̀bẹ mi gé nǹkan?’

Ìkeje wí pé, ‘Taló mu lára ohun-mímu inú ife mi?’

Nígbà náà ni ràrá kìíní náà wò káàkiri. Nígbàtí ó dé ibi ibùsùn rẹ̀, ó bá Funfun Láú tó ti sùn lọ sórí rẹ̀. Ó pe àwọn yòókù, wọ́n sì kóra wọn jọ yíká ibẹ̀ pẹ̀lú ìyanu.

‘Yéèèè!’ wọ́n kígbe. ‘Ọmọbìnrin ló rẹwà tó yìí!’

Wọn kò jìi sílẹ̀, wọ́n jẹ́ kí ó sùn jálẹ̀ òru náà sórí ibùsùn kékèré náà.

Nígbàtí ó di òwúrọ̀, Funfun Láú ta jí. Ní àkọ́kọ́, ẹ̀rú bàá nígbàtí ó rí àwọn ràrá méje náà, ṣùgbọ́n wọ́n yọ̀ mọ́ọ. Wọ́n bèèrè orúkọ rẹ̀.

‘Funfun Láú,’ ó fèsì.

‘Kílódé tí o fi wà sílé wa?’ àwọn ràrá náà bèèrè.

Funfun Láú sọ fún wọn pé aya bàbá òun, ayaba, rán òun lọ sínú igbó láti lọ pa òun. Ó ṣàlàyé bí alénipa náà ṣe dá òun sílẹ̀, àti bí òun ṣe ní láti sáré la igbó kọjá kí òun tó rí ilé wọn.

Àwọn ràrá náà gbà pé kí ó máa gbé lọ́dọ̀ àwọn. Bíi pàṣípààrọ̀, Funfun Láú ní òun yóò máa se oúnjẹ fún wọn, òun yóò sì máa tún ilé wọn ṣe.

Nítorí náà, Funfun Láú bẹ̀rẹ̀ ìgbé-ayé rẹ̀ tuntun nínú igbó náà. Ní òwúrọ̀ ọjọ́ gbogbo, àwọn ràrá náà yóò lọ saarin ibití àpáta wà láti lọ gbẹ́lẹ̀ fún wúrà. Nígbàtí wọ́n bá padà délé nírọ̀lẹ́, Funfun Láú yóò ti se oúnjẹ alẹ́ wọn sílẹ̀ fún wọn.

Jálẹ̀ ọjọ́ gbogbo, wọn yóò fi ọmọdébìnrin náà sílẹ̀ ni òun nìkan, nítorí náà, àwọn ràrá náà kìlọ̀ fún un pé:

‘Ṣọ́ra fún aya bàbá rẹ. Kì yóò pẹ́ kí ó tó mọ̀ pé o wà níbí. Ohunkóhun yòówù tí ìwọ bá ń ṣe, máṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọ inú ilé wá.’

Nísìnyí, ayaba náà gbàgbọ́ pé òun ti jẹ ìfun àti ẹ̀dọ̀ Funfun Láú. Kò ronú nígbà kan pé òun kọ́ ni obìnrin tó rẹwà jùlọ ní gbogbo àgbáyé lẹ́ẹ̀kansíi. Nítorí náà, ó wo ara rẹ̀ nínú dígí rẹ̀ lọ́jọ́ kan, ó sì wí pé:

‘Dígí, dígí ara ògiri,
Ta ló rẹwà jùlọ nínú gbogbo ènìyàn?’

Dígí náà dáhùn:

‘Arábìnrin Mi, ìwọ rẹwà lótìítọ́,
Ṣùgbọ́n Funfun Láú rẹwà jù ọ́ lọ.
Ní ìsọdá àwọn òkè, pẹ̀lú àwọn ọkùnrin kékeré méje,
Ni Funfun Láú, arẹwà tó rẹwà jùlọ, ti padà ń gbé.’

Inú ayaba náà ru sókè pẹ̀lú ìbínú. Ó mọ̀ pé alénipa rẹ̀ pa irọ́ fún òun ni, àti pé Funfun Láú wà láàyè. Dígí onídán náà a máa sọ òtítọ́ nígbà gbogbo.

Ayaba búburú náà ronú tọ̀sán-tòru nípa ọ̀nà tó lè gbà láti pa Funfun Láú run. Ọkàn ìjowú rẹ̀ kò jẹ́ kí ó sinmi nígbàtí ẹlòmíràn tó rẹwà jùú lọ ṣì wà.

Nígbàtí ó ti ronú ohun tí yóò ṣe, ó ṣe ìyàrí kan, ó sì fi májèlé síi nípasẹ̀ ìdán dúdú. Ó fi ọ̀dà kun ojú ara rẹ̀, ó sì múra bí obìnrin arúgbó kan. Àyípadà rẹ̀ dára dé ibi pé kò sí ẹni tó lè dáa mọ̀. Pẹ̀lú ìwò yìí, ayaba búburú náà wá ilé tí Fufun Láú àti àwọn ràrá méje náà ń gbé lọ. Ó kan ilẹ̀kùn.

Funfun Láú yọjú lójú fèrèsé.

‘Ẹ káàárọ̀ o!’ ó kígbe. ‘Ẹ má binu o. ‘Èmi kò lè jẹ́ kí ẹ wọlé.’

‘Ṣùgbọ́n o lè yọjú, àbi?’ obìnrin arúgbó náà fèsì. Ó na ìyàrí tó jọjú náà sókè fún ọmọbìnrin náà láti rí.

Funfun Láú fẹ́ràn ìyàrí náà púpọ̀ dé ibi pé ó ṣí ọkàn ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ẹ̀tàn. Ó ṣílẹ̀kùn.

‘Súnmọ́ ibí, ọmọ mi. Èmi yóò ya irun rẹ fún ọ dáradára,’ ni arúgbó náà wí.

Funfun Láú kò mọ̀ pé òun wà nínú ewu. Ìyàrí náà kò tíì kan orí rẹ̀ dáradára tán kí májèlé náà tó ṣiṣẹ́. Ó dákú lọ.

‘Ọlọrun ti mú ọ báyìí,’ ayaba búburú náà rẹ́rìn-ín músẹ́. Ó sá padà sí ilé rẹ̀ bí ó ṣe lè sáré tó.

Ó jẹ́ nǹkan ayọ̀ wípé, ìrọ̀lẹ́ ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà ni àwọn ràrá méje náà padà dé ilé. Nígbàtí wọ́n rí òkú Funfun Láú nílẹ̀, wọ́n mọ̀ pé aya bàbá rẹ̀ búburú náà ni yóò ṣe iṣẹ́ búburú náà.

Wọ́n yẹ̀ẹ́wò títí wọ́n fi rí ìyàrí oní-májèlé náà. Lọ́gán tí wọ́n fàá jáde kúrò nínú irun Funfun Láú, ọmọbìnrin náà jí dìde. Ó wá sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún wọn. Àwọn ràrá náà tún kìlọ̀ fún un pé ó gbọ́dọ̀ wà ní ìṣọ́ra, kí ó má sì ṣe ṣílẹ̀kùn iwájú ilé náà fún ẹnikẹ́ni mọ́.

Lọ́gán tí ayaba náà délé, ó lọ siíwájú dígí rẹ̀ láti bèèrè pé:

‘Dígí, dígí ara ògiri,
Ta ló rẹwà jùlọ nínú gbogbo ènìyàn?’

Dígí náà dáhùn:

‘Arábìnrin Mi, ìwọ rẹwà lótìítọ́,
Ṣùgbọ́n Funfun Láú rẹwà jù ọ́ lọ.
Ní ìsọdá àwọn òkè, pẹ̀lú àwọn ọkùnrin kékeré méje,
Ni Funfun Láú, arẹwà tó rẹwà jùlọ, ti padà ń gbé.’

Nígbàtí ó gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ara ayaba náà gbọ́n pẹ̀lú ìbínú. Ó mọ̀ pé Funfun Láú tún ti yè lẹ́ẹ̀kansíi.

‘Funfun Láú yóò kú ni!’ ó kígbe. ‘Kódà bó jẹ́ pé ẹ̀mí mi yóò báa lọ ni!’

Lẹ́yìn náà, ó wọ inú yàrá àṣírí kan lọ, ó sì fi idán rẹ̀ ṣe èso òro-òyìnbó kan tó ní májèlé nínú. Wíwó èso náà dára púpọ̀, pẹ̀lú ẹ̀rẹ̀kẹ́ funfun àti pupa tó dùn-un wò. Ẹnikẹ́ni tó bá ríi ni yóò fẹ́ jẹẹ́, ṣùgbọ́n ẹni tó bá ṣe bẹ́ẹ̀ yóò kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni.

Ayaba náà tún yírapadà lẹ́ẹ̀kansíi. Ó gba àárín igbó bọ́ sí ilé kékèré àwọn ràrá méje náà, ó sì kan ilẹ̀kùn ẹnu ọ̀nà.

Funfun Láú yọjú lójú fèrèsé.

‘Ẹ káàárọ̀ o!’ ó kígbe. ‘Ẹ má binu o. ‘Èmi kò lè jẹ́ kí ẹ wọlé.’

‘Mo ní òro-òyìnbó tó dára kan fún ọ, olùfẹ́ mi ọ̀wọ́n,’ obìnrin arúgbó náà wí.

‘Rárá,’ Funfun Láú dáhùn. ‘Èmi ò lè jẹẹ́.’

‘Ìwọ ọmọ aláìgbọ́n yìí!’ ayaba náà fèsì. ‘Kí ló ń bà ọ́ lẹ́rù? Àbí o lérò pé májèlé wà nínú rẹ̀ ni? Wòó, èmi yóò gé òro-òyìnbó náà sí méjì. Èmi á jẹ apá ibi tó funfun lára rẹ̀, ìwọ sì lè jẹ́ ibi tó pupa.’

Tẹ́lẹ̀, òun ti ṣe òro-òyìnbó náà lọ́nà tó jẹ́ pé apá rẹ̀ kan kò léwu láti jẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé apá kejì ní májèlé nínú.

Ìdánwò ńlá ni èyí jẹ́ fún Funfun Láú. Òro-òyìnbó náà dára púpọ̀ láti wò, Nígbàtí ó ríi pé obìnrin arúgbó náà jẹ apá kan, kò lè mú ara rẹ̀ dúró mọ́. Ó gé díẹ̀ lára òro-òyìnbó náà sẹ́nu, ó sì ṣubú lulẹ̀.

‘Funfun bí ẹgbọ́n òwú, pupa bí ẹ̀jẹ̀, dúdú bí kóró iṣin. Ní ìgbà yìí, kò sí ohun tí yóò gbà ọ́ là,’ ayaba náà sọ pẹ̀lú ẹ̀rín. Ojú rẹ̀ tán pẹ̀lú ìdùnnú. Ó sáré lọ síbi dígí rẹ̀, níkẹyín, dígí sì dáhùn pé:

‘Ìwọ ló rẹwà jùlọ nínú gbogbo ènìyàn.’

Níkẹyìn, ọkàn búburú ayaba náà yọ̀. Ọkàn náà ṣáà yọ̀ dé ìwọ̀n ibití irú ọkàn ibi bẹ́ẹ̀ lè nírètí àti yọ̀ dé.

Nígbàtí àwọn ràrá náà padà dé nírọ̀lẹ́, wọ́n bá Funfun Láú níbi tó sùn sílẹ̀ sí láì lè mira rárá. Wọn gbée sókè láti wò ibi gbogbo bóyá wọn yóò rí ohunkóhun tó ní májèlé nínú. Wọ́n ṣe ohun gbogbo tí wọ́n lè ṣe, ṣùgbọ́n Funfun Láú ti kú, ó sì wà nípò òkú síbẹ̀.

Àwọn ràrá méje náà sun ẹkún papọ̀ fún odidi ọjọ́ mẹ́ta. Níkẹyìn, wọ́n pinnu láti sin Funfun Láú, ṣùgbọ́n ọmọdébìnrin náà ṣì rẹwà púpọ̀ nípò òkú pàápàá, èyí tó mú wọn sọ pé:

‘Àwa kò lè fiípamọ́ sínú ilẹ́ tútù lásán.’

Wọ́n ṣe pósí oní-gíláàsì, wọ́n sì gbée sínú rẹ̀. Wọ́n fi lẹ́tà aláwọ̀ wúrà kọ sórí pósí náà pé ọmọba ló jẹ́ lọ́jọ́ ayé rẹ̀. Àwọn ràrá náà sí gbé pósí náà lọ sórí àpáta. Ọ̀kan lára wọn máa ń dúró sẹ́gbẹ̀ẹ́ pòsì náà nígbà gbogbo láti máa ṣọ́ Funfun Láú. Àwọn ẹyẹ pàápàá wá láti fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn pé Funfun Láú di olóògbé. Ní ìbẹ̀rẹ̀, òwìwí kan wá, lẹ́yìn náà ẹyẹ ìwò, àti níkẹyín ẹyẹ àdàbà.

Funfun Láú sùn sínú pósí náà fún ọjọ́ pípẹ́. Bí ó ṣe rí tẹ́lẹ̀ ló ṣì ṣe máa ń rí nígbà gbogbo, bi ẹni tó ń sùn. Àwọ̀ ara rẹ̀ ṣì funfun bí ẹgbọ́n òwú. Ẹ̀rẹ̀kẹ́ rẹ̀ pupa bí ẹ̀jẹ̀. Irun orí rẹ̀ dúdú bí kóró iṣin.

Ní ọjọ́ kan, ọmọbakùnrin kan wá sí orí àpáta náà. Ó rí pósí náà pẹ̀lú Funfun Láú nínú rẹ̀. Nígbàtí ó ka ohun tí wọ́n fi lẹ́tà wúrà kọ sórí rẹ̀, o yíjú sí ràrá náà ó sì sọ pé:

‘Fún mi ní pósí náà. Èmi yóò fún ọ ní ohun yòówù tí o fẹ́ bí o bá lè fún mi.’

‘Rárá, ràrá náà fèsì. ‘Àwa kì yóò yara pẹ̀lú Funfun Láú fún gbogbo wúrà ilé ayé yìí.

‘Ó dára nígbà náà,’ ọmọbakùnrin náà fèsì. ‘Jọ̀wọ́ fifún mi, nítorí tí èmi kò lè wà láìrí Funfun Láú. Èmi yóò fẹ́ràn rẹ̀ ju ohun gbogbo lọ.’

O sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́ ọkàn dé ibi pé àánú rẹ̀ ṣe àwọn ràrá náà. Wọ́n fún un ni pósí náà. Ọmọbakùnrin náà ní kí àwọn ìránṣẹ́ òun gbé pósí náà sórí èjìkà láti máa gbée lọ.

Nígbà náà, ohun ńlá kan ṣẹlẹ̀. Bí àwọn ìránṣẹ́ náà ṣe ń sọ̀kalẹ̀ láti orí àpáta náà, wọ́n kọsẹ̀. Wọ́n mi pósí náà púpọ̀ dé ibi pé òro-òyìnbó oní-májèlé tí Funfun Láú gé jẹ jáde kúrò ní ọ̀fun rẹ̀. Ó ṣẹ́jú díẹ̀, ó sì la ojú rẹ̀.

Funfun Láú ṣí ìdérí pósí, ó sì dìde jókòó láàyè àti lálàáfíà.

‘Yéèèè! Ibo ni mo wà?’ ó kígbe.

Inú ọmọbakùnrin náà kún fún ayọ̀.

‘Ọ̀dọ̀ mi lo wà,’ ó kígbe. Ó sọ gbogbo ohun tó ṣẹlẹ̀ fún un, ó sì wí pé, ‘Mo fẹ́ràn rẹ ju ẹnikẹ́ni ní gbogbo àgbáyé lọ. Ṣé ìwọ yóò tẹ̀lé mi láti di aya mi?’

Funfun Láú gbà, ó sì bá ọmọbakùnrin náà lọ. Wọ́n ṣe ìgbeyàwó láìpẹ́ lẹ́yìn náà. Ayẹyẹ ìgbéyàwó wọn ládùn púpọ̀.

Aya búburú bàbá Funfun Láú wà lára àwọn tí wọ́n pè síbi ayẹyẹ ìgbéyàwó náà. Nígbà tó ti múra dáradára tán, ó lọ sí ibi dígí rẹ̀, ó sì wí pé:

‘Dígí, dígí ara ògiri,
Ta ló rẹwà jùlọ nínú gbogbo ènìyàn?’

Dígí náà dáhùn:

‘Arábìnrin Mi, ìwọ rẹwà lótìítọ́,
Ṣùgbọ́n ìyàwó tuntun rẹwà jù ọ́ lọ.’

Nígbàtí ó gbọ́ èyí, ibínú rẹ̀ fẹ́rẹ̀ yàá ní wèrè. Ọkàn òjòwú rẹ̀ ń mì kíkan-kíkan, ó sì mọ̀ pé inú òun kò ní dùn títí di ìgbà tí òun bá rí ayaba tuntun náà.

Nígbàtí ó dé ibi ayẹyẹ náà, ó ríi pé Funfun Láú ni ìyàwó tuntun náà. Ọmọbìnrin tí òun ti pa kò kúkú kú náà. Ó ṣe ni láàánú pé ìbínú ayaba búrubú náà ni ó fún un lọ́rùn pa; àwọ rẹ̀ yípadà sí dúdú, ó ṣubúlulẹ̀, ó sì di olóògbé.

Funfun Láú àti ọmọbakùnrin rẹ̀ jọ gbé pọ̀ láyọ̀ pẹ́ títí. Nígbà mìíràn, wọn máa ń lọ sí àárín àwọn àpáta náà, wọ́n sì máa ń lọ kí àwọn ràrá náà. Wọ́n máa ń rántí àwọn ọ̀rẹ́ onínúure tó dúró ti Funfun Láú lọ́jọ́ ìṣòro nígbà gbogbo.

Enjoyed this story?
Find out more here