KidsOut World Stories

Ẹwà Tó Wà Nínú Ìyàtọ̀    
Previous page
Next page

Ẹwà Tó Wà Nínú Ìyàtọ̀

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

Ẹwà Tó Wà Nínú Ìyàtọ̀

Ìtàn Ìráànì Kan

 

 

 

 

 

*

Shirin jẹ́ ọmọdébìnrin kékeré kan nígbàtí àwọn òbí rẹ̀ rán-an kúrò nílé rẹ̀ ní Tehrani láti lọ gbé ní ìlú ńlá kan ní Ingilandi ní Lọndọnu.

Shirin kò fẹ́ràn pé kí òun lọ máà gbé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ àbúrò ọ̀kan nínú àwọn òbí rẹ̀ ní Ingilandi, ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ sọ fún un pé, ‘Ohun tó dára jùlọ ni èyí, ọmọ mi. Ààbò wa níbí kò dájú mọ́, ìwọ yóò gbé ìgbé-ayé tí yóò mú inú rẹ dùn ní Ingilandi, ìwọ yóò sì ni oríṣiríṣi ọ̀rẹ́ tuntun.’

Shirin fẹ́ búsẹ́kún nítorí ó fẹ́ràn ìyá àti bàbáa rẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, kò sì fẹ́ fi wọ́n sílẹ̀. Bákan náà, kò mọ àwọn ọmọ ọ̀kan nínú àwọn òbí rẹ̀ náà tẹ́lẹ̀rí rárá. Ẹ̀ẹ̀kanṣoṣo ni wọ́n ti wá kí wọn rí, Shirin kò sì tíì dàgbà tó láti ní òye ohun tí wọ́n ń sọ nítorí wọn kò sọ èdè Farsi, ohun tí Shirin kà sí ohun àjèjì.

Ọjọ́ náà dé, ìyá àti bàbáa Shirin fi ọkọ̀ gbée lọ sí ibùdókọ̀-òfurufú níbití àǹtí rẹ̀ kan yóò ti sìn-ín lọ sínú ọkọ̀-òfurufú.

‘Ẹ̀rù ń bà mí,’ Shirin wí fún wọn, bí bàbá àti ìyáa rẹ̀ ṣe ń tẹ̀lée lọ sábẹ́ àtíbàbà kékeré kan níbití ọkùnrin kan yóò ti yẹ ìwé-ìrìnnà rẹ̀ wò, ti yóò sì wo ìwé-ọkọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú.

‘Kí ló ń bà ọ́ lẹ́rù?’ bàbáa rẹ̀ bèèrè. ‘Ìwọ kọ́ ni ọmọdébìnrin tó gbóyà náà, tí kìí bẹ̀rù nígbàtí a bá ń gbọ́ tí àwọn àdó-olóró bá ń bà sórí ìlú wa bí? Àbi ìwọ sì kọ́ ni ọmọdébìnrin tó máa ń ní kí a mú òun lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ lójoojúmọ́ nígbàtí ìbẹ̀rù-bojo bá ti mú àwọn ọmọdébìnrin yòókù dúró nílé ti àwọn òbí wọn bí?’

‘Ìyẹn yàtọ̀,’ Shirin dáhùn. ‘Ilé mi nìyí.’

Ìyá Shirin kúnlẹ̀ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ọmọdébìnrin náà, ó fàá mọ́ra, ó sì fọwọ́ paá lórí. Ó wí fún ọmọdébìnrin rẹ̀: ‘Mo mọ̀ pé ìwọ yóò wú wa lórí, ọmọ mi. Máṣe bẹ̀rù, láìpẹ́, èmi àti bàbáa rẹ yóò wá sí Ingilandi, ìwọ yóò sì lè fi gbogbo ohun tójú lè wò hàn wá ni Lọndọnu. Mo lè sọ àsọdájú pé ìwọ yóò ti máa sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì dáradára ju bí o ṣe ń sọọ́ ní báyìí lọ, ìwọ yóò sì lè kọ́ mi ní àwọn ọ̀rọ̀ tuntun díẹ̀ síi.’

Shirin fẹ́ràn ìrònú pé òun yóò lè kọ́ ìyá òun ní àwọn ọ̀rọ̀ tuntun nítorítí Shirin rò pé ìyá òun ni ẹni tó gbọ́n jùlọ ní gbogbo àgbáyé.

‘Mo rò pé èmi yóò lè ṣe ìyẹn,’ ọmọdébìnrin náà fèsì, bí àǹtí rẹ̀ ṣe ń fa ọwọ́ rẹ̀ láti ṣàlàyé fún un pé àsìkò ti tó láti wọlé sínú ọkọ̀-òfurufú kí ó tó já wọn sílẹ̀.

Lásìkò irìn-àjò ojú òfurufú náà, Shirin gbìyànjú láti ronú nípa bí ìgbé-ayé rẹ̀ tuntun yóò ṣe rí. Ó pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ láti ṣe dáradára ní ilé-ẹ̀kọ́, ó sì sọ fún ara rẹ̀ pé òun yóò mú ìwúrí bá àwọn òbí òun.

‘Mo lè seé, ó rò lọ́kàn ara rẹ̀. ‘Mo lè ṣe èyí ní ìrọ̀rùn bí ìrọ̀rùn tí mo fi ń ṣa òdòdó.’

Lẹ́yìn náà, ọmọdébìnrin náà sùn lọ, ó sì lá àlá ohun tí Lọndọnu yóò jẹ́. Ó lá àlá àwọn aago tó ga sókè àti àwọn odò tó fẹ́, ó ríi lójú ìran pé: àwọn ọkùnrin wọ àkẹtẹ̀ ńlá, àwọn obìnrin lo agbòòrùn, àwọn ọkọ̀-akérò pupa àti ilé ńláńlá wà níbití Ayaba ń gbé pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ tó ń ṣọ́ ilé rẹ̀ tí wọ́n dé fìlà ńlá, tí wọ́n sì wọ bàtà ńlá pẹ̀lú.

*

Ṣùgbọ́n nígbàtí ó dé ibùdókọ̀-òfurufú ní Lọndọnu, kò rí bí ó ṣe rò rárá. Ojú ọ̀run náà ní àwọ̀ gíréè tí kò wu ni rárá, afẹ́fẹ́ líle ń fẹ́, òjò sì ń rọ̀. Shirin ronú pé òun kò bá tí wọ sálúbàtà nítorí àwọn ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ tutù púpọ̀. Ohun tó sì burú jùlọ ni pé ... Ohun tó burú jùlọ ni èrò tó ní pé gbogbo ènìyàn ni ó ń wo òun bí ẹni pé òun jẹ́ àjèjì tó ní orí ńlá àti ojú mẹ́ta.

Shirin ṣàkíyèsi pé òun nìkan ni òun wọ aṣọ-ẹlẹ́hàá. Ọmọdébìnrin kan tó dúró nítòsí rẹ̀ nawọ́ síi, ó ń rẹ́rìn-ín, ó sì bèèrè lọ́wọ́ ìyá rẹ̀ pé: ‘Kílódé tó ṣe fi aṣọ ńlá bo gbogbo ara rẹ̀ bẹ́ẹ̀ yẹn?’

Ìyá náà fa ọmọbìnrin kékeré náà kúrò, ó sì sọ fún un pé àrínfín ni pé kí ènìyàn máa nawọ́ sí ẹlòmíràn. Shirin fẹ́ sọ fún ọmọdébìnrin náà pé kìí ṣe aṣọ ńlá, aṣọ-ẹlẹ́hàá ni, bẹ́ẹ̀ sì ni ní Tehrani, ọ̀pọ̀ ọmọdébìnrin àti àwọn ìyá àti ìyá ìyá wọn ló máa ń wọ aṣọ-ẹlẹ́hàá nítorí ó jẹ́ ara àṣà wọn.

Dàjúdájú, Shirin fẹ́ bọ́ aṣọ-ẹlẹ́hàá rẹ̀ kúrò nítorí tí kò fẹ́ kí wọ́n máa wo òun bẹ́ẹ̀, ó sì fẹ́ kó jẹ́ pé òun wà ní Tehrani padà, níbití òòrùn ti ń yọ, tí àwọn ìka ẹsẹ̀ rẹ̀ yóò sì lè padàbọ̀sípò.

‘Jẹ́ kí a máa lọ sílé,’ àǹtí rẹ̀ fàá ní kíá wọ inú ọkọ̀ taksi ńlá dúdú kan tó ní iná aláwọ̀ ọsàn lórí.

Shirin ronú pé awakọ̀ taksi náà ń sọ̀rọ̀ lọ́nà tó ń panilẹ́rìn-ín púpọ̀. Kò dàbíi olùkọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì rẹ̀, Ọ̀gbẹ́ni Rahimi rárá. Ó sọ àwọn ohun kan bíi ‘Ó yàmílẹ́nu’ àti ‘ó dára olùfẹ́, ibo ni ẹ̀ ń lọ?’ Ọmọ kékeré Shirin kò mọ ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ṣùgbọ́n ó jọ pé ó yé àǹtí rẹ̀, ọkọ̀ náà sì ti ń gbé wọn lọ ní kíá kọjá laarin ìlú náà lọ sí ilé rẹ̀ tuntun.

Shirin fẹ́ bèèrè lọ́wọ́ àǹtí rẹ̀ ìdí tí kò ṣe wọ aṣọ-ẹlẹ́hàá ní Ingilandi bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń wọ̀ọ́ nígbàtí ó bá wá kí ìyá rẹ̀ ni Tehrani. ‘Ó ń láti máa farapamọ́ ni,’ ọmọdébìnrin náà rò nínú ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n Shirin tún rántí pé ìyá òun ti sọ fún òun pé kò sì àǹfàní kankan nínú fífi ara ẹni tòótọ́ pamọ́ fún àwọn ẹlòmíràn, nítorí náà, Shirin ń ro ohun tó lè fàá ti àǹtí rẹ̀ fi yàn láti wà ní ìfarapamọ́ ní Ingilandi.

Lọndọnu padà jẹ́ ibi tó ṣàjèjì gidi. Òjò ń rọ̀ lójoojúmọ́ ní gbogbo ọ̀sẹ̀ kìíní, Shirin kò sì fi bẹ́ẹ̀ rí ohun tó wuni nípa ìgbà ooru àwọn ara Biriteeni rárá. Kò rọrùn fún un láti gbọ́ ohun tí àwọn ènìyàn ń sọ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti wí fún un pé ó jáfáfá nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì. Ó sì wà jásí pé kìí ṣe gbogbo ènìyàn ni ó lè lọ kí Ayaba nínú ilé ńlá rẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lè fẹ́rẹ́ tó ọgọ́rùn-ún yàrá tó wà níbẹ̀ fún gbígbàlejò àti fún mímu tíì.

Inú ọmọdébìnrin náà kò dùn rárá nígbà to rí ilé rẹ̀ tuntun, aáyun ìyá, bàbá àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sì ń yun-ún. Oúnjẹ ibẹ̀ pàápàá yàtọ̀: ó jẹ́ aláwọ̀ gíréè bíi ti ojú-ọjọ́ ibẹ̀, ó sì dàbí èyí tó máa ń ti inú àwọn àpótí jáde láti inú ẹ̀rọ amú-nǹkan-dì, yàtọ̀ sí àwọn oúnjẹ ìyá rẹ̀ bíi loobia polo pẹ̀lú saffron, tàbí tah‐deeg tó ní àwọ̀ tó wu ni, tó sì máa ń dùn láti jẹ.

Nígbàtí ọjọ́ náà dé fún Shirin láti lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ rẹ̀ tuntun, ara rẹ̀ kò balẹ̀ rárá, ó sì gbìyànjú láti sọ fún àǹtí rẹ̀ pé ara òun kò dá rárá láti dìde kúrò lórí ibùsùn.

‘Èmi kò fẹ́ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́,’ ó kọ̀ jálẹ̀. ‘Èmi kò mọ ẹnikẹ́ni níbẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń fẹjú mọ́ mi!’

‘Àwọn ọmọdébìnrin pọ̀ ní ilé-ẹ̀kọ́ tó ń wọ aṣọ-ẹlẹ́hàá bíi tirẹ̀, ọmọ mi,’ àǹtí rẹ̀ fèsì. ‘Mo mọ̀ dájú pé ìwọ yóò yan ọ̀rẹ́ púpọ̀ lónìí, ìwọ ṣáà máa wòó.’

Ṣùgbọ́n kò rí bẹ́ẹ̀ rárá, pàápàá ní ìbẹ̀rẹ̀. Àwọn ọmọdébìnrin mìíràn wà lótìítọ́ tó wọ aṣọ-ẹlẹ́hàá, ṣùgbọ́n gbogbo wọn ni wọ́n ju Shirin lọ, wọn kò sì báa sọ̀rọ̀.

Àwọn ọmọdébìnrin tó wà ní yàrá ìkàwé tirẹ̀ ń nawọ́ síi, wọ́n sì ń rẹ́rìn-ín. Irun orí gbogbo wọn jẹ́ pupa rẹ́súrẹ́sú tàbí pupa kíkákò, pẹ̀lú ẹyinjúu búlúù, wọn kò si fẹ́ bá ọmọbìnrin tuntun náà ṣọ̀rẹ́ nítorítí ó yàtọ̀ sí wọn, ara rẹ̀ dúdù, ẹyinjú rẹ̀ dúdú, ó si wọ aṣọ̀-ẹlẹ́hàá. Kò dùn mọ́ọ nínú pé ó jẹ́ ẹni tó yàtọ̀ sí àwọn yòókù, Shirin sì fẹ́ kó jẹ́ pé òun wà nílé òun padà pẹ̀lú ìyá òun.

Àsìkò isinmi láti jẹ oúnjẹ ọ̀sán tó, bí ó sì ti jókòó sí ẹ̀gbẹ́ kan lórí pàpà-ìṣeré, tó ń ronú bí òun yóò ṣe sá padà lọ sí Tehrani, ni ọmọdékùnrin kan sunmọ́ Shirin.

‘Orúkọ mi ni Stephen,’ ọmọdékùnrin náà wí. ‘Ṣé kí n fún ọ ní díẹ̀ lára àpòpọ̀ wààrà mi bí?’

Pẹ̀lú èyí, ọmọdékùnrin náà fún Shirin lára àpòpọ̀ wààrà aládùn rẹ̀ tó ní igi tí a fi ń fa ohun-mímu mu lórí.

Shirin lérò pé ohun-mímu náà ládùn púpọ̀, ó sì ní láti dá ara rẹ̀ dùrò kí ó má baà mu gbogbo rẹ̀ tán.

‘Má da àwọn yòókù lóhùn rárá. Wọ́n máa ń hùwà tí kò dára sí èmi náà pàápàá nígbà mìíràn nítorí ti èmi ń bá ìyá mi gbé. Bàbá mi fi wá sílẹ̀ lọ láti ìgbà tó ti pẹ́, àwa méjèèjì nìkan sì ni ó kù nísìnyí. Ìyá mi ní òye tó ga, ó sì máa ń tọ́jú mi dáradára gan-ni, ṣùgbọ́n àwa ko lówó lọ́wọ́ púpọ̀, wọn a sì máa fi mi ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí tí wọ́n sọ pé èmi jẹ́ tálákà, mo sì máa ń wọ aṣọ tó dọ̀tí. Stephen bojúwo aṣọ àwọ̀sókè rẹ̀, àti bàtà rẹ̀, ó sì gún èjìká. ‘Wọn kò dọ̀tí rárá, wọ́n kan ti gbó ni.’

Lójijì, omọdékùnrin náà kúsẹ́rìn-ín. ‘Wọ́n kàn gọ̀ ni o jàre. Kí ni wọ́n mọ̀!’

Shirin rẹ́rìn-ín nítorí pé ẹ̀rín Stephen mú kí ojú rẹ̀ dára láti wò, pẹ̀lú irunmú ńlá tó wà lójú rẹ̀, èyí to wáyé nítorí tó fẹnu lásán mu wààrà rẹ̀ tààrà láti inú ìgò, pẹ̀lú ariwo ọ̀nà-ọ̀fun rẹ̀ tó ń dún síta.

Ọmọdébìnrin náà ní láti sọ òtítọ́ fún ara rẹ̀ pé òun kò tíì jẹ́ kí èrò ẹlòmíràn mú ìrònú bá òun rí, nítorí náà, kílódé tí òun yóò fi wá bẹ̀rẹ̀ nísìnyí?

‘Òótọ́ lo sọ,’ ó dáhùn. ‘‘Kí ni wọ́n mọ̀, àbí!’ Ní pàṣípààrọ̀ fún fífún un ní wààrà rẹ̀, Shirin fa baklava ẹyọ mẹ́rin yọ láti àpo rẹ̀, ó sì bá ọ̀rẹ́ tuntun rẹ̀ ṣàjọpín àkàrà òyìnbó aládùn náà.

‘Mo rò pé aṣọ ìborí rẹ dára láti wò, ni Stephen wí, bí ó ṣe ń du odidi baklava náà jẹ lẹ́ẹ̀kan náà.

‘Aṣọ-ẹlẹ́hàá ni à ń pèé,’ ó wí fún un.

Ọmọdèkùnrin náà tún orúkọ náà pè lẹ́nu rẹ̀ pẹ̀lú baklava aládùn náà tó kún ẹnu rẹ.

‘Ó mà dára púpọ̀ láti wò o,’ ó wí.

Lẹ́ẹ̀kan náà, Stephen fa aṣọ-àwọ̀sókè rẹ̀ sókè láti fi borí kí òun náà báa lè wọ ohun tó jọ mọ́ aṣọ-ẹlẹ́hàá. Shirin kò lè ṣàì má rẹ́rìn-ín nítorí tí ọmọdékùnrin náà dàbí oníyẹ̀yẹ́. Ó ronú pé ìyá àti bàbá òun yóò fẹ́ràn Stephen púpọ̀ nítorí tí ó jẹ́ ènìyàn tó ní okun nínú, tó sì máa ń ronú nípa àwọn ohun tó máa ń mú inú ènìyàn dùn, ohun tí ìyá Shirin máa ń sọ pé ó dára púpọ̀ fún àwọn ènìyàn láti máà ṣe.

Láìpẹ́, àwọn méjèèjì ti gbàgbé ara wọn sínú eré àròṣe àti ìrìnkèrindò wọn, wọ́n ń sáré kiri ni ẹ̀gbẹ́ kan lórí pápá-ìṣeré náà, wọ́n ń lé ara wọn káàkiri. Wọ́n sọ ìtàn fún ara wọn, Shirin sì sọ fún Stephen nípa ìgbé-ayé ní Tehrani, bẹ́ẹ̀ ni Stephen náà sì sọ fún Shirin nípa àwọn nǹkan dáradára tí ènìyàn lè ṣe ní Lọndọnu, bíi ṣíṣeré nínú ọgbà ńlá tàbí lílọ sí ilé àwọn ẹranko tàbí sinimá. Kẹ̀kẹ́ ńlá kan tún wà tí ènìyàn lè ṣeré lórí rẹ̀.

‘Wọ́n kọ́ọ sí ẹ̀bá odò Thames gan-gan. Ó tóbi púpọ̀!’ ó kígbe bí ó ṣe ń fi ọwọ́ ya òbirìkìtí kan sínú afẹ́fẹ́.

Kò pẹ́ kí àwọn ọmọdé tó kù fi ṣàkíyèsi bí Shirin àti Stephen ṣe ń dárayá pẹ̀lú ìdùnnú, láìpẹ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kó ara wọn jọ yípo, wọ́n sì ń bá wọn kópa nínú eré àti ìtàn wọn.

Kí agogo tó dún láti pe àwọn ọmọdé náà padà lọ sí yàrá ìkàwé wọn, àwọn ọmọdé kan ti kó ara wọn jọ láti tẹ́tisí Shirin tó ń sọ ìtàn nípa ìgbésí-ayé rẹ̀ ní Tehrani, nípa bí ó ṣe farapamọ́ sábẹ́ ibùsùn rẹ̀ nígbàtí ó gbọ́ bí àwọn àdó-olóró ṣe ń jábọ́ sílẹ̀ láti ojú ọ̀run, tàbí nípa bí ó ṣe máa ń lọ kí àbúrò àwọn òbí rẹ̀ kan tó burú púpọ̀, tó ń gbé ní ilé ńlá lẹ́bàá odò, níbití òun tí máa ń lọ lo ìsinmi. Ẹnu ya àwọn ọmọdé náà láti gbọ́ irú ìtàn bẹ́ẹ̀, wọn kò sì lè ṣàì má bèèrè àwọn oríṣiríṣi ìbéèrè ti inú Shirin sì dùn púpọ̀ láti dàhùn.

Shirin náà bèèrè padà lọ́wọ́ àwọn náà nípa Ingilandi, àti ìdí tó fi jẹ́ pé òtútù ibẹ̀ pọ̀ púpọ̀ bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àkókò ooru ni wọ́n wà, àti ìdí tó fi jẹ́ pé Ayaba kìí fẹ́ gbàlejò. Èyí mú kí àwọn ọmọdé náà rẹ́rìn-ín.

Ní òpin ohun gbogbo, olùkọ́ ní láti wọ inú pápá-ìṣeré náà wá láti wá pe àwọn ọmọdé náà padà sí yàrá ìkàwé wọn nítorí tí wọn kò tilẹ̀ gbọ́ nígbàtí agogo dún nítorí ìdùnnú wọn nípa ọ̀rọ̀ tí wọ́n ń sọ.

Bí ó ṣe ń rìn kọjá lórí pápá-ìṣeré náà, ọkàn Shirin ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Stephen nítorí ó ti fi ohun kan tó ṣe pàtàkì púpọ̀ hàn-án.

‘Kò sí ohun tó burú nípa yíyàtọ̀,’ ó sọ fún ara rẹ̀, ‘ní tòótọ́, ohun tó dára púpọ̀ ni.’ Pẹ̀lú èrò yìí ní oókan àyà rẹ̀, Shirin ṣe ìpinnu láti gbé ìgbé-ayé tuntun ní Ingilandi, àti láti wú àwọn òbí rẹ̀ lórí. ‘Taló mọ̀,’ ó rò nínú ara rẹ̀, ‘ó lè jẹ́ pé nígbàtí ìyá àti bàbá mi bá dé ibí, wọn yóò mọ̀ bí mo ṣe lè lọ kí Ayaba.’

Enjoyed this story?
Find out more here