KidsOut World Stories

Ọkọ̀-akérò lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́    
Previous page
Next page

Ọkọ̀-akérò lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

 

 

Ọkọ̀-akérò lọ sí Ilé-ẹ̀kọ́
 

 

 

 

 

 

 

 

 *

Ohun tí Joaquin fẹ́ràn jùlọ nípa Ingilandi ni ọkọ̀-akérò. Òun àti ìyá rẹ̀ a máa wọ ọkọ̀ náà lójoojúmọ́ lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ Joaquin tuntun. Ó fẹ́ràn láti máa wo gbogbo àwọn oríṣiríṣi èrò tó ńwọ ọkọ̀.

Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn tó ń lọ sí ibi-iṣẹ́ wọn ni wọ́n máa ń sábà jókòó nínú ọkọ̀ náà. Wọ́n a máa wọ aṣọ tó mọ́ tóní, wọn sì máa ń gbé àpò àti àpótí ibi-iṣẹ́ kékeré dání. Àwọn ìjókòó inú ọkọ̀ yòókù ni àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ bíi Joaquin máa ń jókòó sí. Ọ̀pọ̀ lára wọn jẹ́ ẹni tó dàgbà ju òun lọ, wọn sí máa ń wọ aṣọ ilé-ẹ̀kọ tó bára wọn mu.

Ọ̀kan lára àwọn èrò inú ọkọ̀ tí Joaquin fẹ́ láti máa wo ni obìnrin onírun funfun kan. Ó gbé ajá aláwọ̀ pupa rẹ́súrẹ́sú kékeré kan sínú àpò rẹ̀. Arábìnrin náà sọ pé ajá náà máa ń bẹ̀rù. Joaquin máa ń gbìyànjú láti fọwọ́ pa ajá náà lára nígbà gbogbo.

Joaquin ko fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì púpọ̀, ṣùgbọ́n ìyá rẹ̀ gbọ́ dáradára. Bí wọ́n bá ti wọ inú ọkọ̀ akérò náà, ìyá náà yóò bèèrè iye owó ọkọ̀. Awakọ̀ èrò náà yóò tẹ ìwé-owó ọkọ̀ wọn jadé.

Ní gbogbo òwúrọ̀, òun yóò sọ pé, ‘Ìwé owó ọkọ̀ àlọ àti àbọ̀ sí Blackfriars.’ Nígbàtí wọ́n bá sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ èrò náà, yóò jẹ́ kí Joaquin sọ pé ‘ẹ ṣeun púpọ̀.’ Ọ̀rọ̀ náà dábí èyítí kò mọ́ ọ lára, ṣùgbọ́n òun kọ́ láti máa sọ ọ́, ó sì mọ̀ọ́ sọ.

Púpọ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ilé-ẹ̀kọ́ Joaquin jẹ́ elédè Gẹ̀ẹ́sì. Òun a máa sábà dá jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan nínú yàrá ìkàwé. Olùkọ́ rẹ̀ jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́, ṣùgbọ́n ojú máa ń ti Joaquin. Ó máa ń fèsì sí ìbéèrè pẹ̀lú ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan, kìí sì nawọ́ sókè rárá. Ẹ̀rù a máa bàá láti sọ ohun tí kò tọ́ ní èdè Gẹ̀ẹ́sì. Kò fẹ́ láti máa sọ gbólóhùn ọ̀rọ̀ tí kò nítumọ̀ tàbí tí kò pè bó ṣe yẹ. Joaquin fẹ́ kọ́ láti máa sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì rẹ̀ láì ṣe àṣìṣe kankan rárá kó tó máa sọ ọ́, ṣùgbọ́n òun kò wá ààyè láti kọ́ ọ dáradára.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù Kejìlá, ìyá Joaquin kò àrùn ọ̀fìnkì. Ó wọ aṣọ tó nípọn fún ara rẹ̀ àti Joaquin. Ó fi gèlè to gún bo ọrùn ara rẹ̀. Òtútù ti ń mú Joaquin tẹ́lẹ̀, ṣùgbọ́n ìgbà òtútù ní Briteeni a máa burú púpọ̀.

Òtútù náà múu títí wọ inú ìka rẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń rìn lọ sí ibùdó ìwọkọ̀, ìyá rẹ̀ ń gbọ̀n, ó sì ń wúkọ́. Joaquin gbá ọwọ́ rẹ̀ tútù mú.

Ọkọ̀ èrò náà dé, wọ́n sì dúró kí àwọn èrò yòókù wọlé ná. Ìyá Joaquin wúkọ́ lẹ́ẹ̀kansíi, ó sọ pé, ‘Bèèrè iye owó ọkọ̀, Joaquin.’

Joaquin míkanlẹ̀. Ó wọ inú ọkọ̀ náà, ó sì wo ojú gbogbo ènìyàn. Bó ṣe máa ń rí, ọ̀pọ̀ ènìyàn ló wà níbẹ̀. Wọ́n kọjú mọ́ fóònù àti ìwé wọn. Arábìnrin arúgbó náà pẹ̀lú ajá rẹ̀ nìkan ni ó ń wòkè. Arábìnrin náà rẹ́rìn-ín sí Joaquin.

Pẹ̀lú ìgboyà díẹ̀ síi, Joaquin kọjú sí awakọ̀ èrò náà, ó sì sọ pẹ̀lú ohùn rẹ̀ tó fi ọ̀wọ̀ ńlá hàn pé, ‘Ìwé owó ọkọ̀ méjì lọ sí Blackfries.’

Awakọ̀ èrò náà kọjú síi, ojú rẹ̀ fihàn pé ìbéèrè náà kò yée, ‘Blackfries?’

Ojú Joaquin yípadà sí pupa nítorí ìtìjú, ‘Sí Blackfries. Blackfries ni ilé-ẹ̀kọ́ mi wà.’

‘Àbí Blackfriars lo fẹ́ sọ?’

‘Bẹ́ẹ̀ni,’ Joaquin fi orí dáhùn.

Lára àwọn èrò inú ọkọ̀ yòókù gbé orí sókè kúrò ní fóònù tí wọ́n kọjú mọ. Ó dàbí pé inú ń bí wọn pé Joaquin ń dá wọn dúró. Lọ́gán tí ìyá Joaquin ti sanwó láti gba ìwé owó ọkọ̀ tán, ọmọ náà gbá ọwọ́ ìyá rẹ̀ mú, ó sì gbìyànjú láti fojú pamọ́.

Ojú ń ti Joaquin. Ó fẹ́ ran ìyá rẹ̀ lọ́wọ́ ni, ṣùgbọ́n ńṣe ló kùnà láti lè ṣeé. Bó ti ń sún imú, ilẹ̀ ni Joaquin ń wò jálẹ̀ ìrìn-àjò náà. Nígbàtí wọ́n bọ́ sílẹ̀ láti inú ọkọ̀ èrò náà, Joaquin kò sọ ‘ẹ ṣeun’ sí awakọ̀ èrò náà bí òun ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀. Ìyá rẹ̀ ni ó dúpẹ́ lọ́wọ́ awakọ̀ náà fúnrarẹ̀.

Jálẹ̀ gbogbo ọjọ́ náà, Joaquin dákẹ́ jẹ́ẹ́ ju bí ó ti máa ń ṣe tẹ́lẹ̀rí lọ. Kò gbìyànjú láti bá olùkọ́ rẹ̀ sọ̀rọ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé olùkọ́ náà wá ọ̀nà láti jẹ́ kí ó sọ̀rọ̀ sí òun. Kò tó ẹni tó lè sọ̀rọ̀ nítorí kí òun má baà ṣe àṣìṣe mìíràn.

Nígbàtí ìyá Joaquin lọ múu ní ilé-ẹ̀kọ́, ara rẹ̀ ti balẹ̀ díẹ̀ ju ti òwúrọ̀ lọ.

Ó rẹ́rìn-ín sí Joaquin ó sì dì mọ́ ọ, ‘Mo lérò pé ọjọ́ rẹ lọ dáradára?’

Joaquin kò fèsì.

Ìyá rẹ̀ kúnlẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀, ó sì fọwọ́ pa á lórí, ‘Joaquin, kílódé?’

‘Ojú ti ń tì mí, mo sì ti ń ṣe àníyàn nípa èdè Gẹ̀ẹ́sì mi látàárọ̀. Mo gbìyànjú láti ràn ọ́ lọ́wọ́, ṣùgbọ́n mi ò lè ṣeé. Mò ń fẹ́ kí èdè Gẹ̀ẹ́sì mi jẹ́ aláìlábàwọ́n, ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí láti sọ̀rọ̀. Yóò rọrùn láti sọ̀rọ̀ tó bá jẹ́ pé gbogbo ènìyàn ní Ingilandi ń sọ èdè Speeni tàbí èdè mìíràn tí mo gbọ́. Ó ti le jú. Mo fẹ́ máa lọ sílé.’

Ìyá Joaquin fetísìlẹ̀ láti gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí.

Nígbàtí Joaquin sinmi díẹ̀ láti nu omi ojú rẹ̀ nù, ìyá rẹ̀ sọ pé, ‘Pẹ̀lẹ́ ọkọ mi. Kíkọ́ ohun tuntun máa ń gba àsìkò. Ìyẹn yé mi. Nítorí tí o jẹ́ ọmọ rere ló mú kí o fẹ́ ràn mí lọ́wọ́. O ṣeun.’

Ó fi ẹnu ko iwájú orí rẹ̀, ‘O kò nílò láti jẹ́ ẹni tó mọ ohun gbogboó ṣe. Kò sí ẹni tó mọ ohun gbogboó ṣe. O kàn nílò láti ní ìgboyà ni.’ Ó rẹ́rìn-ín músẹ́, ‘Ò ń ṣe dára dára púpọ̀, ìwà rẹ sì ń wú mi lórí. Máṣe sọ ìrètí nù, Joaquin.’

Joaquin fi orí dáhùn.

Bí wọ́n ṣe ń lọ sí ibùdó ìwọkọ̀, ó ronú nípa ọ̀rọ̀ ìyá rẹ̀, ó sì ríi pé òtítọ́ ni ó ń sọ. Àwọn ènìyàn tó dára jùlọ pàápàá máa ń ṣe àṣìṣe nígbà mìíràn. Joaquin ronú pé ohun tó mú wọn jẹ́ ẹni tó pé jùlọ ni pé wọ́n dìde nílẹ̀ láti gbìyànjú ní ọjọ́ kejì. Bí òun bá lè ní ìgboyà, tí òun sì gbé orí ara òun sókè, òun yóò lè ṣe ohunkóhun.

Ọkọ̀ èrò náà dé láti gbé wọn padà lọ sílé. Ọkọ̀ èrò náà kún bó ṣe máa ń rí, Joaquin sì ṣàkíyèsi àwọn ènìyàn tó wọ kóòtù àti ṣòkòtò, àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́, àti àwọn obìnrin tó mú ajá dání, gbogbo wọn ǹ bá ara wọn sọ̀rọ̀ lórí fóònù. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìgboyà, bí wọ́n bá sì ṣe àṣìṣe kankan, wọn yóò rẹ́rìn-ín nípa rẹ̀.

Nígbàtí wọ́n dé ibití wọn yóò ti sọ̀kalẹ̀, Joaquin àti ìyá rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ láti inú ọkọ̀ èrò náà, Joaquin sì kọjú sí awakọ̀ èrò náà pẹ̀lú ìgboyà tó hàn kedere, ‘Ẹ ṣeun!’

Awakọ̀ èrò náà rẹ́rìn-ín, ó sì dúpẹ́ padà lọ́wọ́ rẹ̀. Bí Joaquin àti ìyá rẹ̀ ṣe ń rìn lọ sílé, ó pinnu pé àṣìṣe kìí ṣe ohun tó burú pátápátá.

Enjoyed this story?
Find out more here