KidsOut World Stories

Ọ̀rẹ́ Tòótọ́ Noel White    
Previous page
Next page

 

 

 

 

Ọ̀rẹ́ Tòótọ́

Ìtàn Kan Ní Èdè Gẹ̀ẹ́sì

 

 

 

 

 

*

Ẹbí Yasin ṣí kúrò ni Ìráàkì lọ sí Íngíláǹdì nígbàtí òun ṣì jẹ́ ọmọdé lásán. Yasin kò fẹ́ lọ kúrò ní ilé rẹ̀ tó wà ní Samarra ṣùgbọ́n bàbáa rẹ̀ sọ fún un pé ohun tó dára jùlọ fún ìdílé wọn nìyẹn nítorí pé ààbò wọn kò dájú bí wọ́n bá tẹ̀síwájú láti máa gbé níbẹ̀, àti pé òun ń fẹ́ kí ọmọ òun dàgbà sí orílẹ̀-èdè tó ń gba gbogbo ènìyàn mọ́ra. Bàbá Yasin sọ fún ọmọ rẹ̀ pé Ingilandi jẹ́ orílẹ̀-èdè tó ní oríṣiríṣi àṣà níbití àwọn ènìyàn jọ ń gbé pọ̀, tí wọ́n sì jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ láì ka ẹ̀yà tàbí ẹ̀sìn wọn sí.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé inú Yasin kò dún sí fífi Ìráàkì sílẹ̀, ó tètè gba kámú nípa ìgbé-ayé rẹ̀ tuntun ní ìlú ńlá kan tí à ń pè ní Lọndọnu. Lọndọnu jẹ́ ìlú tó dun-ún wò pẹ̀lú àwọn ilé ńláńlá àti ilé ìtọ́jú àwọn ohun ìtàn àti àṣà rẹ̀, Yasin sì fẹ́ràn ilé ńlá tí à ń pè ní London Planetarium ati odò ǹlá tí à ń pè ní River Thames pẹ̀lú àwọn afárá àtijọ́ tó gba orí rẹ̀ kọjá.

Yasin tún yan ọ̀rẹ́kùnrin kan tó ń gbé nílé kejì sí tirẹ̀, tó ń jẹ́ Anderu. Jálẹ̀ gbogbo àsìkò ọdún tí òòrùn ń yọ, Anderu àti Yasin máa ń ṣeré lórí pápá tàbí kí wọ́n lọ sí ọgbà àwọn ẹranko pẹ̀lú ìyá Anderu. Anderu ṣàjọpín àwọn ohun ìṣeré rẹ àti àwọn ìwé ọmọdè apanilẹrin rẹ pẹ̀lú Yasin, òun a sì máa sọ nípa àwọn akọni alágbára ńlá rẹ tó fẹ́ràn jùlọ fún un pẹ̀lú. Wọ́n tilẹ̀ kọ́ ibi ìpàgọ́ kan sínú ọgbà tó wà lẹ́yìn ilé Yasin, níbití wọ́n máa ń sá pamọ́ sí fún àwọn àgbàlagbà.

Àsìkò òòrùn jẹ́ àsìkò ìgbádùn, ara ọmọdékùnrin Yasin sí tètè bẹ̀rẹ̀ sí mọ ilé ní Lọndọnu, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú ńlá ni ìlú náà, tí òòrùn kìí sì fi bẹ́ẹ̀ mú bíi ó ti rí ni Samarra. Èdè Gẹ̀ẹ́sì rẹ̀ ń dára síi, pàápàá jùlọ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Anderu, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ ló wà tí kò tíì yé Yasin, tí ojú a sì máa tìí nígbà púpọ̀ nítorí tí kò lè sọ èdè náà dáradára bó ṣe fẹ́.

Nígbàtí ó di oṣù Kẹsàn-án ọdún tí àwọn ewé bẹ̀rẹ̀ sí jábọ́ lára àwọn igi, bàbáa Yasin ṣàlàyé pé àsìkò tó fún ọmọ òun láti bẹ̀rẹ̀ ilé-ẹ̀kọ́. Yasin ti pé ọmọ ọdún méje, nítorí náà yóò máa lọ sí ipele ọdún kẹta ní ilé-ẹkọ́ alakọbẹ̀rẹ̀ àdúgbò - ipele ọdún kan náà pẹ̀lú Anderu ọ̀rẹ́ rẹ̀!

Lóòtọ́ ara Yasin kò tètè yá sí lílọ sí ilé-ẹ̀kọ́, bàbá àti ìyá rẹ̀ fií lọ́kàn balẹ̀ pé ibẹ́ yóò jẹ́ ibi ìdùnnú fún un, níbití òun yóò ti pàdé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ tuntun, tí yóò sì kọ́ ọ̀pọ̀ àwọn ohun tuntun tí yóò dùn mọ́ọ nínú.

‘Àwọn ilé-ẹ̀kọ́ Gẹ̀ẹ́sì yẹ kó jẹ́ èyí tó dára gidi,’ ni ìyá Yasin wí.

‘Èdè Gẹ̀ẹ́sì rẹ yóò sì dára síi láìpẹ́,’ bàbá rẹ̀ náà sì sọ èyí láti fií lọ́kàn balẹ̀.

Gbogbo èyí kò tíì mú kí Yasin ní ìdánilójú, ṣùgbọ́n nígbàtí Anderu kan ilẹ̀kùn ilé rẹ̀ pẹ̀lú ẹ̀rín ńlá lẹ́nu rẹ, tó sì ń sọ bí ohun gbogbo yóò ṣe ládùn tó ní ilé-ẹ̀kọ́, ọkàn Yasin balẹ̀ díẹ̀ síi nítorí tí ó ní ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rẹ́ rẹ̀.

Àwọn ọmọdékùnrin méjèèjì ṣàròyé títí wọ́n fi dé ẹnu-ọ̀nà ilé-ẹ̀kọ́ náà. Anderu ti sọ fún Yasin nípa pápá-ìṣeré àti ẹni tó jẹ́ olùkọ tó dára jùlọ àti àwọn ọmọdékùnrin tó dùn-ún bá ṣeré àti àwọn ọmọdébìnrin tó rẹwà jùlọ àti iye ìgbà tí wọ́n máa ń pèsè ògì òyìnbó fùn mímu lé oúnjẹ ọ̀sán. Yasin kò mọ ohun tí ògì òyìnbó jẹ́, ṣùgbọ́n ojú Anderu kún fún ẹ̀rin nígbàtí ó ń sọ èyí fún un, nítorí náà, Yasin ronú pé ó gbọ́dọ̀ jẹ́ ohun tó dùn púpọ̀.

Ṣùgbọ́n nígbàtí àwọn ọmọdékùnrin náà dé yàrá ìkàwé wọn, ohun gbogbo kò lọ bí Yasin ṣe rò pé yóò lọ. Olùkọ́ sọ fún Anderu pé kí ó jókòó níwájú ní yàrá ìkàwé náà, ó sì fi Yasin han àwọn ọmọdé yòókù nínú yàrá náà. Kò fẹ́ràn bí òun ṣe dìde dúró síwájú àwọn ọmọdé yòókù, ọmọdékùnrin kan sì kígbe sókè láti pèé ní àjèjì olóòórùn. Gbogbo àwọn ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin náà kúsẹ́rìn-ín, ọmọdékùnrin mìíràn sì tún fi Yasin ṣe yẹ̀yẹ́ nítoríi bí ó ṣe ń sọ̀rọ̀ nígbàtí wọ́n ní kí ó sọ orúkọ rẹ̀ àti ibití ó ti wá.

‘Ohun tó ń wí kò yé mi, olùkọ́. Kò tilẹ̀ lè sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì pàápàá,’ ni ọmọdékùnrin ẹlẹ́rẹ̀kẹ́-èébú náà wí.

Níkẹyìn, wọ́n jẹ́ kí Yasin lọ jókòó sẹ́yìn nínú yàrá ìkàwé náà ṣùgbọ́n òun kò bá fẹ́ láti jókòó ti Anderu torí tí ó rí ara rẹ̀ bí ẹnití kò ní alábàárò kankan rárá. Ọmọdébìnrin tó jókòó sẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ ń fi ojú ẹ̀gbẹ́ kan wòó bákan bákan, èyí sì mú kí ara Yasin má balẹ̀, bí ìkẹ́kọ̀ọ́ sì ṣe ń lọ, ọmọbìnrin náà nawọ́sókè láti bèèrè lọ́wọ́ olùkọ́ bóyá òun lè jókòó síbòmíràn. Yasin kò mọ ohun tí òun ṣe fún ọmọdébìnrin náà.

Nígbàtí wọ́n lu aago, àsìkò tó láti lọ sí pápá-ìṣeré lóde. Gbogbo àwọn ọmọdé náà pa ìwé wọn dé, wọ́n wọ aṣọ àwọ̀sókè (kóòtù) wọn, wọ́n sì jáde lọ sábẹ́ òòrùn tó ń ràn ní ọjọ́ náà to bọ́ sí àárìn ìgbà ooru àti ìgbà òtútù. Olùkọ́ dá Yasin dúró díẹ̀ sí yàrá ìkàwé, ó fún un ní báàjì àlẹ̀máyà kan tí a ti kọ orúkọ rẹ̀ sí, ó sì lẹ̀ èyí mọ́ aṣọ rẹ̀.

‘O lè máa lọ ní báyìí,’ ni olùkọ́ wí pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́ kan. ‘Nísìnyí gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ yóò lè mọ orúkọ rẹ.’

Yasin rò pé báàjì àlẹ̀máyà náà dàbí ohun tí kò bójúmu, nígbàtí ó sì bọ́ sóde sí pápá-ìṣeré, gbogbo àwọn ọmọdé náà bẹ̀rẹ̀ sí nawọ́ síi, wọ́n sì fi ń ṣe yẹ̀yẹ́.

‘Orúkọ obìnrin ni ìwọ ńjẹ́,’ ni ọmọdékùnrin onírun kíkákò pupa kan wí.

Yasin fẹ́ ṣàlàyé fún un pé kìí ṣe orúkọ obìnrin ṣùgbọ́n ọkàn rẹ̀ ń gbọ̀n gidi. Bí ọkàn Yasin bá ti ń gbọ̀n bẹ́ẹ̀, èdè Gẹ̀ẹ́sì sísọ rẹ̀ kìí sábà já gaara, òun a sì máa kálòlò. Inú rẹ̀ bàjẹ́ gidi, ó sì fẹ́ sá kúrò lórí pápá-ìṣeré náà padà lọ sọ́dọ̀ ìyá àti bàbáa rẹ̀ láì padà wá sí ilé-ẹ̀kọ́ náà mọ́. Ṣùgbọ́n bí ó ṣe fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí sá lọ, ó gbọ́ ohun kan tó ti dá mọ̀.

‘Báwo ni Yasin.’ Bí ó sì ti wòkè, ó rí Anderu tó dúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Anderu wo gbogbo àwọn ọmọdé tó kórawọnjọ yíká, ó sì mi orí rẹ̀. ‘Kí ló ń ṣe gbogbo yín ná?’ ó bèèrè. ‘Mo sọ fún ọ̀rẹ́ mi Yasin pé yóò gbádùn ilé-ẹ̀kọ́. Kílódé tí ẹ̀yin ń ba ohun gbogbo jẹ́ fún un?’

‘Ó yàtọ̀ sí wa,’ ọmọdébìnrin gíga kan tó dúró síwájú àwọn èrò náà dáhùn.

‘Bẹ́ẹ̀ náà ni ìwọ náà,’ Anderu fèsì. ‘Ìwọ ni ọmọbìnrin tó ga jùlọ ní gbogbo ilé-ẹ̀kọ́ yìí, inú rẹ̀ kìí sì dùn bí àwọn ènìyàn bá ń fi ọ́ ṣe yẹ̀yẹ́, àbí?’

Anderu wá kọjú sí ọmọdékùnrín onírun kíkájọ pupa náà. ‘Ìwọ náà kìí sí fẹ́ kí àwọn ènìyàn sọ pé irun obìnrin lo ní,’ ó ń bá ọmọdékùnrin náà wí. ‘Gbogbo wa ni a yàtọ̀, èyí ló sì mú kí ohun gbogbo dùn. Báwo ni ayé ò bá ti rí bí gbogbo wa bá rí bákan náà?’

Gbogbo àwọn ọmọdé náà dákẹ́ jẹ́ẹ́.

Yasin wá gbé orí ara rẹ̀ sókè. Ó dáhùn pẹ̀lú ẹ̀rín pé ‘Yóò sú wa ni.’

Anderu kígbe ‘Bẹ́ẹ̀ni!’, ó rẹ́rìn-ín padà sí ọ̀rẹ́ rẹ̀. ‘Yóò sú wa gidi gan!’

Bí ó sì ti sọ èyí, gbogbo àwọn ọmọdé náà bẹ̀rẹ̀ sí rẹ́rìn-ín.

‘Yóò sú wa gidi gan!’ gbogbo wọn pariwo sọ fún ara wọn.

Anderu tẹ̀síwájú láti ṣàlàyé nípa bí òun ṣe lo àsìkò ìsinmi òun pẹ̀lú Yasin, bí àwọn ṣe jọ kọ́ ibi ìpàgọ́, tí àwọn ṣeré nínú ọgbà, àti bi Yasin ṣe fẹ́ràn akọni tí wọ́n ń pè ní Batman ju Superman lọ, àti bí ó ti jẹ́ ẹni tó yàtọ̀ pátápátá torí tí kìí jẹ ohun tí wọ́n ń pè ní họ́tídọọ̀gì!

Àwọn ọmọdé náà túbọ̀ kúsẹ́rìn-ín, láìpẹ́, gbogbo wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ àwọn ohun tó mú wọn yàtọ̀ si ara wọn. Peter Jenkins ká aṣọ rẹ̀ sókè láti fi ààmì àbínimọ̀ dúdú kan tó wà lórí ikùn rẹ̀ han gbogbo wọn.

Ó wà sọ bí ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ borí nínú ìjàkadì kan pé ‘Èyí gan-an ni wọ́n ń pè ní ìyàtọ̀. Mo mọ̀ pé kò sí ẹnikẹ́ni laarin yín tó ní ààmì àbínimọ́ tó tóbi bíi tèmi!’

Nígbàtí àkókò ìṣeré dópin, Anderu nawọ́ rẹ̀ sókè ní yàrá ìkàwé, ó sì dábàá fún olùkọ́ pé kí wọn lo àkókò ìkẹ́kọ̀ọ́ láti fi sọ̀rọ̀ nípa bí ó ṣe dára tó pé gbogbo ènìyàn yàtọ̀ sí ara wọn, àti bí àwọn ènìyàn ṣe wá sí Ingilandi láti ibi gbogbo káàkiri àgbáyé láti bẹ̀rẹ̀ ìgbé-ayé tuntun gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́ rẹ̀ Yasin ṣe ṣe.

Olùkọ́ gbà pé ó ṣe pàtàkì láti jẹ́ ẹni ọ̀tọ̀, ó sì tún sọ nípa bí ó ti dára tó pé gbogbo orílẹ̀-èdè Biriteeni jẹ́ erékùṣù tó ní oríṣiríṣi àṣà. Yasin kọ ọ̀rọ̀ méjèèjì wọ̀nyí sílẹ̀ nínú ìwé rẹ, ó sì pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé òun yóò kọ́ ọ̀rọ̀ méjèèjì, óun yóò sì máa rántí wọn nígbà gbogbo. Ó tún kọ ‘ọ̀rẹ́’ náà sílẹ̀ nínú ìwé rẹ̀. Ó ti mọ ohun tí èyí túmọ̀ sí, ṣùgbọ́n ó kàn fẹ́ kọọ́ sílẹ̀ ni nítorí tí ó mọ̀ rírì níní ọ̀rẹ́ tó dára bíi Anderu tó lè dúrótini nígbà ìṣòro, tí kò sì kíí dánilẹ́bi nítorí tí wọ́n yàtọ̀ síi àwọn ènìyàn mìíràn ní àyíká.

 

Enjoyed this story?
Find out more here