KidsOut World Stories

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti Ẹyẹ Àkọ̀ Mary Smith    
Previous page
Next page

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti Ẹyẹ Àkọ̀

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

Cloud logo

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti Ẹyẹ Àkọ̀

 

 

  

 

 

 

 

 

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ àti ẹyẹ àkọ̀ jọ ń gbé pọ̀ nínú igbo.

Ní ọjọ́ kan, kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ pe ẹyẹ àkọ̀ láti wá bá òun jẹun.

‘Arábìnrin Àkọ̀, wá ní ọ̀la ní aago méjìlá,’ ó wí.

Inú ẹyẹ àkọ̀ dùn púpọ̀, ó sì lọ sí ihò kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ọjọ́ kejì.

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ gbé ọbẹ̀ tó ládùn sílẹ̀. Ó bùú sínú àwo pẹlẹbẹ.

‘Òórùn ìyẹn mà dára o!’ ni ẹyẹ àkọ̀ wí.

Ẹyẹ àkọ̀ gbìyànjú láti jẹun ṣùgbọ́n ìṣòro kan wà. Ẹnu gígùn ẹyẹ àkọ̀ kò ṣeé jẹ ìwọ̀n ọbẹ̀ tó kéré jùlọ pàápàá rárá. Àwo náà ti pẹlẹbẹ jù.

‘Yéèèè! Ó mà s̩e o!’ kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà kégbe. ‘Èmi yóò ní láti bá o̩ je̩ oúnje̩ re̩.’

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà je̩ gbogbo o̩bè̩ náà tán.

E̩ye̩ àkò̩ padà sílé. Ebi ń paá.

‘Hmm,’ ó rò nínú rè̩. ‘Jàǹdùkú ni kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀. Kí ni mo lè s̩e láti kó̩o̩ ló̩gbó̩n?’

Ó ronú díè̩ síi. ‘Aha!’ ó kígbe. ‘Ohun kan ti wá sórí mi.’

Ó padà pe kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ láti wá je̩un nílé rè̩.

‘Wá ní ò̩la ní ìgbà tí òòrùn bá kan àtàrí, Arákùnrin Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀’ ó wí.

Ó lo̩ sílé láti se o̩bè̩ aládùn kan.

Inú kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ dùn púpò̩. Ó dé ilé e̩ye̩ àkò̩ ní aago méjìlá ní o̩jó̩ kejì.

O̩bè̩ náà wà nínú irú ìgò tí à ń fi òdòdó sí, èyí tó ní o̩rùn tó gùn sókè. Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ náà kò lè kó o̩bè̩ náà lá, ebi sì ń paá púpò̩.

‘Yéèèè! Ó mà s̩e o!’ e̩ye̩ àkò̩ náà kégbe. ‘Èmi yóò ní láti bá o̩ je̩ oúnje̩ re̩.’

E̩ye̩ àkò̩ náà ki e̩nu rè̩ gígùn sínú ìgò òdòdó náà, ó sì fa gbogbo o̩bè̩ náà mu tán.

‘S̩e fún mi kí ń s̩e fún o̩!’ e̩ye̩ àkò̩ kégbe.

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ padà sí ilé rè̩ pè̩lú ìrù rè̩ laarin e̩sè̩ rè̩.

Enjoyed this story?
Find out more here