KidsOut World Stories

Búrọ́ọ̀ṣì Ọ̀dà Onídán    
Previous page
Next page

 

 

 

 

Búrọ́ọ̀ṣì Ọ̀dà Onídán

Ààlọ́ Ṣainíìsì Kan

 

 

 

 

 

*

Nígbà kan rí, ọ̀dọ́mọkùnrin kan wà tí à ń pè ní Ma Liang. Ó jẹ́ aláìní, onínúure, ó sì fẹ́ràn láti máa yàwòrán dé ibi pé ó máa ń yàwòrán síbi gbogbo. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, ó lá àlá pé ọkùnrin arúgbó kan fún òun ní búrọ́ọ̀ṣì ọ̀dà onídán kan, ó sì ní kí òun máa lòó láti fi ran àwọn aláìní lọ́wọ́. Nígbàtí ó ta jí, ó rí búrọ́ọ̀ṣì onídán náà lórí tábílì rẹ̀.

Láti ọjọ́ náà lọ, òun máa ń lo búrọ́ọ̀ṣì ọ̀dà onídán náà nígbà yòówù tí àwọn ènìyàn aláìní bá nílò ìrànlọ́wọ́. Nígbàtí ó bá ríi pé àwọn ènìyàn kò ní omi láti lò ní pápá oko, yóò yàwòrán odò, àwòrán náà yóò sì di odò tí a lè fojúrí lótìítọ́. Àwọn ènìyàn yóò sì lè pọn omi láti odò náà lọ sórí pápá oko láti mú àwọn ohun ọ̀gbìn wọn dàgbà. Nígbàtí ó bá rí àwọn àgbẹ̀ tó ń ṣiṣẹ́ takun-takun tí wọ́n ń gbìyànjú láti bọ́ àwọn ìdílé wọn, yóò yàwòrán oúnjẹ púpọ̀ síi fún wọn láti jẹ. Láìpẹ́, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn mọ̀ nípa búrọ́ọ̀ṣì ọ̀dà onídán náà, wọ́n sì dúpẹ̀ púpọ̀ lọ́wọ́ Ma Liang.

Ṣùgbọ́n arakùnrin ọlọ́rọ̀ kan wà tó ń gbé ní abúlé, ó jẹ́ awun ènìyàn, ó sì pinnu láti jí búrọ́ọ̀ṣì ọ̀dà náà lọ́wọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin náà kí ó báa lè lòó láti mú kí ọrọ̀ rẹ̀ túbọ̀ pọ̀ síi. Nítorí náà, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sí ilé Ma Liang láti lọ jí búrọ́ọ̀ṣì ọ̀dà onídán náà.

Lọ́gán tó ti ní búrọ́ọ̀ṣì ọ̀dà náà lọ́wọ́, inú rẹ̀ dùn púpọ̀, ó sì pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti wá sí ilé rẹ̀ kí ó báa lè fi ohun-ìní rẹ̀ tuntun hàn wọ́n. Ó ya ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwòrán, ṣùgbọ́n kò sí èyí tó yípadà di ohun tí a lè fojúrí lótìítọ́ lọ́wọ́ rẹ̀. Inú bíi gidi pé búrọ́ọ̀ṣì ọ̀dà náà kò ṣiṣẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀, nítorí náà, ó ránṣẹ́ pe Ma Liang.

Ó wí fún ọ̀dọ́mọkùnrin náà pe, “Bí o bá lè ya àwọn àwòrán kan fún mi, tí o sì mú wọn wà láàyè ní tòótọ́, èmi yóò dá ọ sílẹ̀.”

Ma Liang kò fẹ́ ran irú ènìyàn búburú báyìí lọ́wọ́, ṣùgbọ́n ọgbọ́n kan wá sí orí rẹ̀.

Ó wí fún arákùnrin búburú náà pé, “Kíni ìwọ yóò fẹ́ kí n yà?”

Arákùnrin náà fèsì pé, “Mo fẹ́ àpáta oníwúrà. Èmi yóò máa lọ síbẹ̀ láti lọ kó wúrà jọ.”

Ṣùgbọ́n ọ̀dọ́mọkùnrin náà kọ́kọ́ yàwòrán odò ńlá kan.

Inú bí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ ná, ó sì sọ pé, “Kílódé tí o fi yàwòrán odò ńlá? Àpáta oníwúrà ni mo fẹ́. Yàwòrán rẹ̀ ní kíá!”

Nítorí náà, ọ̀dọ́mọkùnrin náà yàwòrán àpáta oníwúrà tó jìnnà sì odò náà.

Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà wí pé, “Yàwòrán ọkọ̀ ojú omi ńlá ní kíá. Mo fẹ́ lọ síbẹ̀ lọ kó wúrà jọ.”

Ọ̀dọ́mọkùnrin náà rẹ́rìn-ín músẹ́, ó sì yàwòrán ọkọ̀ ojú omi ńlá. Ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà bẹ́ sínú ọkọ̀ ojú omi náà, ó sì ń lọ láti wá wúrà náà ṣùgbọ́n nígbàtí ọkọ̀ ojú omi náà dé àárín odò ńlá náà, Ma Liang yàwòrán ìjì ńlá kan tó ba ọkọ̀ ojú omi náà jẹ́, wọn kò sì rí ọkùnrin ọlọ́rọ̀ náà mọ́ ní abúlé náà.

Lẹ́yìn èyí, ọ̀dọ́mọkùnrin náà gbé pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀ láyọ̀, tí ó sì máa ń lo búrọ́ọ̀ṣì ọ̀dà onídán náà láti ran àwọn ènìyàn aláìní lọ́wọ́ gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin arúgbó náà ti ní kí ó máa ṣe, gbogbo ènìyàn ni ó sì mọ búrọ́ọ̀ṣì ọ̀dà onídán náà, wọ́n sì fẹ́ràn rẹ̀.

Enjoyed this story?
Find out more here