KidsOut World Stories

Ègún Vasconcelos Monteiro    
Previous page
Next page

Ègún

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

Ègún

Ìtàn Pọtugí Kan

 

 

 

 

 

*

Nígbà kan tó ti pẹ́ púpọ̀, abúlé kékeré kan wà léti igbó ńlá kan. Abúlé tí àláfíà máa ń wà níbẹ̀ nígbà púpọ̀ ni, ṣùgbọ́n àwọn ara ibẹ́ máa ń gbé pẹ̀lú ibẹ́rú-bojo fún àwọn tí wọ́n ń pè ní Lobizon, àwọn ẹni tó ń gbé láàárín igbó níbi tó jìnnà réré. Àwọn Lobizon jẹ́ ẹ̀dá dúdú, ìdajì ara wọn jẹ́ ti ènìyàn, ìdajì jẹ́ ti kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀, ní gbogbo àsìkò tí òṣùpá bá sì yọ lẹ́kùnrẹ́rẹ́, a gbọ́ pé àwọn ìṣẹ̀dá wọ̀nyìí máa ń yọ́ jáde láti inú igbó láti wá ẹran ara ènìyàn.

Ṣùgbọ́n báwo ni irú àwọn ẹ̀dá bẹ́ẹ̀ ṣe wáyé? Ìyẹn rọrùn: ègún tó wà lórí èyíkéyìí ọmọ keje tí ìdílé yòówù bí. Egún náà kìí ṣẹ lé àwọn ọmọ obìnrin lórí, ṣùgbọ́n bí ìyá kan bá bí ọmọ ọkùnrin méje, èyí tó jẹ́ ìkeje láàárín àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyìí yóò padà di Lobizon dájúdájú.

Nígbàtí wọ́n bí Filipe, ẹ̀rù ń ba ìyá rẹ̀. Ọmọ obìnrin ni ó nírètí àti bí, kìí ṣe ọmọkùnrin keje; ìyá Filipe jẹ́ onínúure àti ẹni to nífẹ̀ẹ́, òun kò sì ní fẹ́ kọ ẹ̀yìn sí ọmọ rẹ̀, ohun yòówù kí àwọn ara àbùlé náà lè sọ nípa ègún náà.

Ọ̀pọ̀ ọdún kọjá làìsí wàhálà. Filipe dàgbà di ọmọdékùnrin tó lókun púpọ̀ nínú, èyítí ìyá, bàbá àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ mẹ̀fẹ̀ẹ̀fà fẹ́ràn púpọ̀. Ṣùgbọ́n Filipe kò lè ṣàì ṣàkíyèsi pé a kìí ṣe òun bí a ṣe ń ṣe àwọn ẹ̀gbọ́n òun yòókù. Kò lè lọ sí ilé-ẹ̀kọ́ nítorí olùkọ́ kò gbàá láàyè. Èyí kò yẹ bẹ́ẹ̀ nítorí ọmọdékùnrin náà fẹ́ràn láti máa kọ́ nípa ohun tuntun, ó si fẹ̀ púpọ̀ láti bá àwọn ọmọ mìíràn ṣe ọ̀rẹ́.

Bí ìya Filipe bá ṣèṣì rán-an láti lọ ra búrẹ́dì wá, àwọn ènìyàn abúlé náà kò jẹ́ súnmọ́ ibi tó wà, wọ́n sì máa ń wòó pẹ̀lú àdàpọ̀ ìbẹ̀rù àti ìkórìíra, èyí tó ń mú kí ọkàn ọmọdé náà má balẹ̀. Àwọn ọmọdé yòókù kò jẹ́ báa ṣeré, wọn kìí sì gbàá láàyè láti bọ́ síta lọ ṣeré nínú ọgbà bí òṣùpá bá ti yọ lẹ́kùnrẹ́rẹ́. Ohun tí a mẹ́nubà kẹ́yìn yìí ni èyí tó burú jù nínú gbogbo rẹ̀ nítorípé Filipe fẹ́ràn òṣùpá púpọ̀, nǹkan kan nípa rẹ̀ – pàápàá jùlọ nígbàtí ó bá yọ lẹ́kunrẹrẹ, tó si rí roboto lálẹ́ lójú ọ̀run – máa ń bá Filipe sọ̀rọ̀, ó máa ń ru ọ̀kan rẹ̀ sókè, ó sì máa ń jẹ́ kí ó fẹ́ kọrin, kí ó fẹ́ jó, àti kí ó fẹ́ sáré.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun gbogbo ń lọ déédé láìsí wàhálà, ayọ̀ kò sí níbẹ̀. Filipe ń bá ara rẹ̀ bí ẹniti à ń kọ̀silẹ̀ síi lójoojúmọ́ bí ọdún ṣe ń gorí ọdún. Kò ní ọ̀rẹ́ kankan, wọn kò sì pèé rí láti wá bá ọmọdé yòówù ṣeré. Nígbà mìíràn, yóò máa gbọ́ bí wọ́n ṣe ń rẹ́rìn-ín, ó sì máa ń ronú irú eré tí wọ́n lè máa ṣe, àti bí inú wọn ṣe ńdùn sí. Filipe tún ṣàkíyèsi pé ìyá àti àwọn ẹ̀gbọ́n òun pàápàá ti bẹ̀rẹ̀ sí wo òun bákan bákan.

‘Kí ló ṣe mi gan-an ná?’ Filipe máa ń bèèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ nígbà gbogbo. ‘Èmi kìí ṣá ṣe ọmọ burúkú. Mo máa ń ṣiṣẹ́ mi, mí ò sì kí ń hùwà àìtọ́. Kílódé tí wọ́n fi ń hùwà sí mi lọ́nà tó yàtọ̀ sí ti àwọn ọmọdé mìíràn?’

Bí ó ti ń súnmọ́ ọjọ́-ìbí rẹ̀ kẹẹ̀dógún, inú Filipe bàjẹ́ gidi. Ìyá rẹ̀ kò gbàá láàyè mọ́ láti jáde nínú ilé rárá, ẹ̀rù sì máa ń bàá púpọ̀ tó bá wà lọ́dọ̀ rẹ̀. Àwọn ọmọ burúkú máa ń sọ òkúta lùú bí wọ́n bá ríi níbi tó ti ń ṣeré lẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n bí ó bá yípadà láti kojú wọn, wọn yóò sá lọ pẹ̀lú ariwo ńlá bí ìgbà tó jẹ́ abàmì. Nígbà míì, yóò dàbí pé kí Filipe sá lọ sínú igbó ńlá, kí ó má sì padà wá mọ́.

Ní ọjọ́ kan, ìyá rẹ̀ pèé jókòó láti ṣàlàyé ìdí ìṣòrò rẹ̀ fún un. ‘Ìwọ ni ọmọkùnrin mi keje,’ ó sọ fún un, ‘ègún kan sì wà lórí rẹ, ọmọ mi.’

Ọ̀rọ̀ náà kò yé Filipe rárá. ‘Irú ègún wo?’ Ó bèèrè.

‘Ní ọjọ́ tí o bá pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún, ìwọ yóò yípadà di Lobizon, ẹ̀dá kan tó jẹ́ ìdajì ènìyàn, ìdajì kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀.’

Filipe mọ̀ nípa Lobizon nípasẹ̀ àwọn ìwé rẹ̀ àti àwọn ìtàn tí àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ máa ń sọ fún ara wọn lálẹ́ nígbà yòówù tí wọ́n bá rò pé ó ti sùn lórí ibùsùn rẹ̀. Ṣùgbọ́n wọn kò tíì sọ fún Filipe rí pé ègún kankan wà lórí rẹ̀. Kò fẹ́ di Lobizon rárá. Kò fẹ́ jẹ́ ìkà ènìyàn tàbí ènìyàn búburú, èrò níní èékánná tó gùn àti kìkì irun lára kò si dáa lójú rárá.

Ní òru ọjọ́ tó yẹ kó pé ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún, inú Filipe bàjẹ́ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. Ó dìde jókòó lórí ibùsùn rẹ̀ láàárín ọ̀gànjọ́ òru, ó sì sun ẹkún kíkorò. ‘Mo ti máa ń dá wà nígbà gbogbo.’ ó ronú.

‘Wọ́n ti máa ń yà mí sọ́tọ̀ nígbà gbogbo. Nísìnyí, ègún wà lórí mi láti di Lobizon. Kí ni mo lè ṣe? Ohun tí mo fẹ́ láyé mi ni pé kí wọ́n máa hùwà sí mi bí wọ́n ṣe ń ṣe sí gbogbo ènìyàn. Ohun tí mo fẹ́ láyé mi ni pé kí n lè ṣeré nínú igbó pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi, kí n sì lè wo òṣùpá tó dára lálẹ́.’

Lásìkò náà Filipe wo ìta láti ojú fèrèsé yàrá rẹ̀, ó sì ṣàkíyèsi pé òṣùpá ń yọ jáde láti ojú ọ̀run tó dúdú, tó sì kún fún ìràwọ̀. Òṣùpá ńlá náà dára púpọ̀, ó sì mù kí ayọ̀ kún ọkàn rẹ̀. Nígbà náà, ohun àjèjì kan ṣẹlẹ̀. Ohun kan ń ro inú Filipe pọ̀, ará sì bẹ̀rẹ̀ síí yún un. Láti àyà rẹ̀, ohun kan bẹ̀rẹ̀ sí pariwo bí ẹranko, ó sì gbé orí rẹ̀ sókè sí òṣùpá, ó ń pèé bí kò ti kí ń ṣe tẹ́lẹ̀rí. Ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí yọ irun káàkiri lójijì, àwọn èékánná tó wà lórí ìka ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ yípadà sí èékánná gígùn bíi ti ẹranko. Aṣọ rẹ̀ fàya sí wẹ́wẹ́, ó bọ́ sílẹ̀ kúrò lára rẹ̀. Nígbàtí Filipe wo ara rẹ̀ nínú dígí, ó rí àwòrán ọmọkùnrin-kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ kan tó ń wòó padà, pẹ̀lú irun tó kún ara rẹ̀ àti ojú pupa to ń dẹ́rùbani, èyí tó dàbí èyí tó ń tanná nínú òkùnkùn. 

‘Àṣé Lobizon ni mi nítòótọ́!’ Ó pariwo. 

Filipe gbọ́ tí òṣùpá àti igbó náà ń pe òun, ó sì mọ̀ pé àsìkò ti tó láti kọ ayé òun àtijọ́ sílẹ̀ fún àyànmọ́ rẹ̀.

Kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀-ènìyàn kékeré náà ṣí fèrèsé yàrá rẹ̀. Kí ó tó fò jáde sínú àṣálẹ́ náà, ó dúró láti wo yàrá rẹ̀ àtijọ́ fún ìgbà ìkẹyìn, ó ronú nípa ìyá àti bàbá àti àwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ọkùnrin mẹ́fẹ̀ẹ̀fà. ‘Èmi yóò máa rántí yín láíláí, ẹ̀yin ẹbí mi ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ní báyìí, mo gbọ́dọ̀ faramọ́ irú ènìyàn tí mo jẹ́, kí n sì bẹ̀rẹ̀ ìgbé-ayé tuntun.’

Ó wá fó jáde láti ojú fèrèsé yàrá rẹ̀, ó sáré lọ sínú igbó, ó ń kígbé bi ẹranko sí òṣùpá náà, ọkàn rẹ̀ sì kún fún ìrètí tuntun tó yàtọ̀ fún ọjọ́-iwájú rẹ̀.

Nígbàtí Filipe wọ inú igbó ńlá náà, ó dúró láàárin ibíkan tó dára púpọ̀ tí wọ́n ti ro oko ibẹ́ kúrò, ó wo àwọn igi àtijọ́ àti òṣùpá tó dára tó wà lókè lójú ọ̀run. Ó kígbe léraléra bí ẹranko, ó fò sókè, ó jó, ó rẹ́rìn-ín... nígbà tó sì jájá dá kíkígbe àti jíjó dúró, ó wò káàkiri, ó sì ríi pé àwọn Lobizon mìíràn ló kórajọ síbi tí wọ́n ro náà. Àwọn kan lára wọn ṣì jẹ́ ọmọdé bíi Filipe, àwọn mìíràn ti dàgbà.

Wọ́n súnmọ́ Filipe, wọ́n sì kíi káàbọ̀.

‘O ti délé báyìí, nínú igbó ńlá láàárin àwọn ọ̀rẹ́,’ ọ̀kan lára wọn wí pẹ̀lú ohùn pẹ̀lẹ́ tó fi ìfẹ́ ńlá hàn. Ìgbà náà ni Filipe wá ríi pé kò sí ègún kankan lórí òun rárá.

‘Lobizon ni mí, mo sì ti dèlè!’ Ó wí pẹ̀lú ẹ̀rín lẹ́nu rẹ̀ bó ṣe ń gbé orí sókè láti wo òṣùpá tó ń ràn lẹ́kùnrẹ́rẹ́ náà, ó sì kígbe sòkè pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀. Àwọn Lobizon yòókù darapọ̀ mọ́ọ láti kígbe ńlá sójú ọ̀run àṣàlẹ́ náà ní ìbọ̀wọ̀ fún òṣùpá náà.

Ní ọ̀pọ̀ máìlì níbòmíràn, ìyá Felipe dúró sínú ọgbà rẹ̀, ó wọ aṣọ àwọ̀sùn rẹ̀, ó sì ń gbọ́ orin àwọn Lobizon tó ń bá afẹ́fẹ́ tó ń fẹ́ lẹ́lẹ́ náà wá láti inú igbó ńlá náà. Obìnrin arúgbó náà rẹ́rìn-ín sínú ara rẹ̀ nítorí ó mọ̀ pé ọmọkùnrin òun keje ti wá ilé fún ara rẹ̀ níkẹyìn níbití wọn yóò ti kíi káàbọ̀ àti níbití yóò ti ní ọ̀rẹ́ púpọ̀, tí yóò sì gbé ìgbé-ayé aláyọ̀ fún ìgbà pípẹ́.

Enjoyed this story?
Find out more here