KidsOut World Stories

Àgbọ̀nrín àti Ìjàkùmọ̀ David Heathfield    
Previous page
Next page

Àgbọ̀nrín àti Ìjàkùmọ̀

A free resource from

Begin reading

This story is available in:

 

 

 

 

Àgbọ̀nrín àti Ìjàkùmọ̀

Ìtàn Àwọn Ará Burasili

 

 

 

 

 

 *

Àgbọ̀nrín ń rin lọ lẹ́bàá odò ńlá sínú igbó: ‘Yéèèè, irú ayé wo ni tèmi yìí? Kò sí ilé. Bóyá èmi yóò kọ́lé fún ara mi. Ibí yìí dára bíi ibi yòówù.’

Àgbọ̀nrín tẹ̀síwájú.

Ìjàkùmọ̀ dé sẹ́bàá odò ńlá náà, ó ń fi igi wa ọkọ̀ ojú omi lẹ́gbẹ̀ẹ́ igbó náà. Ó dé ibìkan náà: ‘Yéèèè, kí tilẹ̀ ni ayé mi jẹ́ẹ? Bóyá ní ọjọ́ kan èmi yóò fìdímúlẹ̀ láti pèsè ilé fún ara mi. Ibí yìí yóò dára bíi ibi yòówù.’

Bẹ́ẹ̀ni Ìjàkùmọ̀ náà tẹ̀síwájú.

Àgbọ̀nrín padà dé, ó fi ìwo aláwẹ́ púpọ̀ rẹ̀ ro oko igbó, ó gé àwọn igi, ó mú kí ilẹ̀ náà dọ́gba láti lè kọ́lé fùn ara rẹ̀, ó sì wọ inú igbó lọ padà.

Nísìnyí Ìjàkùmọ̀ dé. ‘Ibí ló yẹ kí n kọ́le mi sí, ṣùgbọ́n wọ́n ti ro oko orí ilẹ̀ náà, wọ́n sì ti mú ilẹ̀ náà dọ́gba. Láìṣàníàní, Ọlọrun Tupani ti bùkún èyí. Ibí ni èmi yóò kọ́ ilé mi sí.’ Pẹ̀lú ìrètí tó ga, Ìjàkùmọ̀ náà mú kí ilẹ̀ ńà túbọ dọ́gba síwájú síi, ó si ṣe ilẹ̀ tó tẹ́jú fún ara rẹ – ó fi eyín ẹnu rẹ̀ mú ilẹ̀ náà le síi, ó sọọ́ di dídán – ó sì wọ inú igbó lọ padà.

Àgbọ̀nrín dé padà. ‘Wọ́n ti ṣe ilẹ̀, tó ń dán, tó sì le. Láìṣàníàní Ọlọrun Tupani ń ràn mi lọ́wọ.’ Pẹ̀lú ọ̀tun agbára, Àgbọ̀nrín kọ́ ògiri fún ilé náà. Nígbàtí ó ṣetán, Àgbọ̀nrín tún gba inú igbó lọ.

Ni Ìjàkùmọ̀ bá dé: ‘Ọlọrun Tupani ti kọ́ ògiri fún ilé mi. Nísìnyí,èmi yóò ṣe òrùlé.’ Ìjàkùmọ̀ alágbára sì ṣe òrùlé, nígbà tó ṣeé tán, ó padà lọ sínú igbó. Àgbọ̀nrín ríi pé wọ́n ti ṣe òrùlé: ‘Tupani ti bùkún mi lótìítọ́.’

Nínú ilé náà, Àgbọ̀nrín ṣe yàrá méjì. Ọ̀kan fún ara rẹ̀ àti ọ̀kan fún Tupani. Ó wọ inú yàrá kan lọ, ó sùn bí alẹ́ ti ń lẹ́.

Nísìnyí Ìjàkùmọ̀ padà dé, ó ríi pé yàrá méjì ti wà nínú ilé náà: ‘Tupani ti ṣe yàrá fún ara rẹ̀ láti lè ṣàjọpín ilé náà pẹ̀lú mi.’

Ó wọ inú yàrá kejì, ó sì sùn lọ.

Àgbọ̀nrín àti Ìjàkùmọ̀ sùn jálẹ̀ àṣálẹ́ náà nínú ilé kan náà. Ní ìdàjí, àwọn mèjèèjì jí.

Àgbọ̀nrín rí Ìjàkùmọ̀. Ìjàkùmọ̀ wo Àgbọ̀nrín. ‘Ṣé o ṣèrànwọ́ láti bá mi kọ́ ilé mi ni?’

‘Mo ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé o ṣèrànwọ́ láti bá mi kọ́ ilé mi ni?’

‘Mo ṣe bẹ́ẹ̀.’

Bí ó ṣe wáyé nìyí tó fi jẹ́ pé Ìjàkùmọ̀ àti Àgbọ̀nrín ṣàjọpín ilé náà ní ìṣọ̀kan ... fún ìgbà díẹ̀.

Ebi ń pa Ìjàkùmọ̀: ‘Lọ dáná. Gbé ìkòkò omi ka iná títí yóò fi hó. Èmi ń lọ ṣe ọdẹ.’ Ìjàkùmọ̀ sì fi ilé náà sílẹ̀, Àgbọ̀nrín ṣètò iná dídá àti ìkòkò omi híhó.

Ìjàkùmọ̀ ṣàwárí àgbọ̀nrín kan, ó gbáa mú, ó sì paá. Ó gbée padà lọ sílé. Ó bẹ̀rẹ̀ sí se àgbọ̀nrín náà. Nígbàtí Àgbọ̀nrín rí ohun tí Ìjàkùmọ̀ ń sè, inú Àgbọ̀nrín bàjẹ́.

Ìjàkùmọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí jẹun. Ẹ̀rù ń ba Àgbọ̀nrín, kò sì jẹun. Àgbọ̀nrín lọ sí yàrá rẹ̀, ó gbìyànjú láti sùn.

Ìjàkùmọ̀ wọ yàrá rẹ̀ lọ.

Ní gbogbo òru náà, Àgbọ̀nrín la ojú rẹ̀ sílẹ̀, ní ìbẹ̀rù pé Ìjàkùmọ̀ yóò wá pa òun jẹ.

*

Ní òwúrọ̀, Àgbọ̀nrín wí fún Ìjàkùmọ̀: ‘Lọ dáná. Gbé ìkòkò ka iná. Gbé omi ka iná títí yóò fi hó. Èmi ń lọ ṣe ọdẹ.’

Àgbọ̀nrín lọ sínú igbó. Níbẹ̀, ìjàkùmọ̀ kan ń fi èèpo igi pọ́n èékánná rẹ̀. Àgbọ̀nrín tẹ̀síwájú títí tó fi rí Tamandua tó máà ń jẹ kòkòrò.

‘Ìjàkùmọ̀ yẹn sọ̀rọ̀ ibi nípa rẹ.’

Inú bi Tamandua. Ó lọ bá ìjàkùmọ̀ náà jà pẹ̀lú èékánná rẹ̀ gígùn tó lágbára. Nígbàtí ó pa ìjàkùmọ̀ náà tán, Tamandua bà tirẹ̀ lọ. Àgbọ̀nrín gbé òkú ìjàkùmọ̀ padà lọ sílé.

Nígbàtí Ìjàkùmọ̀ rí ohun tí Àgbọ̀nrín ń sè, ẹ̀rú bàá. Kò lè máa wò bí Àgbọ̀nrín ṣe ń jẹun, nítorí náà, ó lọ sí yàrá rẹ̀. Ṣùgbọ́n lótìítọ́, àgbọ̀nrín kìí jẹ ẹran ìjàkùmọ̀.

Àgbọ̀nrín wọ inú yàrá rẹ̀ lọ. Àgbọ̀nrín kò lè sùn. Ẹ̀rù ń ba Àgbọ̀nrín pé Ìjàkùmọ̀ yóò wá lálẹ́ láti pa òun jẹ.

Ìjàkùmọ̀ kò lè sùn. Ẹ̀rù ń bàá pé lálẹ́ Àgbọ̀nrín yóò wá láti pa òun jẹ.

Ìjàkùmọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kan orí mọ́lẹ̀ láìpẹ́, ó sì sùn lọ.

Àgbọ̀nrín bẹ̀rẹ̀ sí kan orí mọ́lẹ̀ láìpẹ́, ó sì sùn lọ. Bí orí rẹ̀ ṣe ń kàn mọ́lẹ̀, àwọn ìwo aláwẹ́ púpọ̀ rẹ̀ gbá ògiri, ó sì pariwo. Ìjàkùmọ̀ jí dìde, pẹ̀lú ìbẹ̀rù pé Àgbọ̀nrín tí ń bọ̀ wá pa òun jẹ. Ó kígbe sókè. Àgbọ̀nrín gbàgbọ́ pé Ìjàkùmọ̀ ti ń bọ̀ wá pa òun.

Àgbọ̀nrín sá kúrò ní ilé náà! Ìjàkùmọ̀ sá kúrò ní ilé náà! Àwọn méjèèjì sá lọ ní ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Láti ìgbà náà lọ, Ìjàkùmọ̀ àti Àgbọ̀nrín kò gbé pọ̀.

Enjoyed this story?
Find out more here